Test Embed Page made with 10.1.0 generator and 10.0.5 embed wrapper
Click here for a list of include paths
Click here for a test page with no right hand side
Pese Awọn alaṣẹ Ẹlẹda ni kiakia Rọle si Awọn ọna Iyọlẹnu Eyikeyi ti Ilu India ṣafikun Awọn anfani Agbaye Ni Agbegbe Ayikaṣe Nipa fifun Awọn akiyesi Ọdun Ọdun Forex Lati Ṣẹda Ọfiisi, Ifiranṣẹ Koko Ipo Ipo Rẹ
Alaye ore-aye, aaye wọn ti wo, ijiroro, eto, ọja, bbl, awọn ibi-afẹde ipo-akọkọ jẹ kanna. Ifunni itọsọna itọsọna rira ni a sọ fun. Ni bayi ọrọ koko ominira Gẹẹsi ko sọ taara nipasẹ abala naa. Jaane Dishame Igbimọ Ijumọsọrọ Iṣeduro Itagiri Agbaye Tiaja Ẹgbẹ pataki ṣugbọn
World Cup 22: Àwọn ọ̀nà àrà láti mú pápá ìṣeré tutù ní ìlú aṣálẹ̀
- BBC News Arabic àti World Service Visual Journalism Team
- Ìdíje ìfe ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àgbáyé ti Qatar ti ọdún 2022
Nígbà tí wọ́n yan Qatar gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀èdè tí yóò gbàlejò ìdíjé ife ẹ̀yẹ àgbáyé, àwọn ọ̀rọ̀ kan jẹyọ nípa ìtàn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn orílẹ-èdè náà àti àwọn ìdojúkọ nípa bí àwọn agbábọ́ọ̀lù àti àwọn tó ń wo ìran yóò ṣe ṣe oru ìorílẹ̀èdè náà tó máa ń kọjá 40C.
Ọ̀nà-àbáyọ kan ni kí wọ́n sún ìdíje náà sí ìgbà òtútù. Ṣùgbọ́n orílẹ-èdè aṣálẹ̀ ọ̀hún tó ní owó lọ́wọ́ ṣe àdéhùn pé òun yóò fi ìtàn ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí lélẹ̀: ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun tó lè jẹ́ kí ó ṣeéṣe láti gbàlejò ìdíje ńlá nígbà gbogbo, kódà kọ́ jẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó gbóná jù. Hajar Saleh tó ń gbá bọ́ọ̀lù ní Qatar so pé bí ojú ọjọ́ ṣe gbóná àti ọ̀gìnìǹtìn sọ eré bọ́ọ̀lù di ohun tó ní ìdojúkọ ńlá.
Nítorí náà, báwo ni wọn yóò sọ ayẹ́ dẹ̀rùn fún àwọn agbábọ́ọ̀lù àti àwọn tó wá wò wọ́n láì ná ilé ayé ní nǹkan?
Tẹ̀ẹ́ lọ ilẹ̀ kí o tẹ̀lé afẹ́fẹ́ bó ṣe ń fẹ́ káàkiri pápá ìṣeré Al Janoub, ọ̀kan lára pápá ìṣeré mẹ́jọ tí wọn yóò lò ní Qatar 2022.
Qatar jẹ́ ìlú tó gbóná tó ní ọ̀gìnìǹtìn. Atẹ́gun gbigbóná ń fẹ́ káàkiri orílẹ̀-èdè kékeré náà.
Ìdójǔkọ àkọ́kọ́ ni láti sé atẹ́gùn gbígbóná ọ̀hún mọ́ ìta. Ní pápá ìṣeré Al Janouon, wọ́n ṣe òkè rẹ̀ bí yóò ṣe máa darí afẹ́fẹ́ sí òkè ọ̀nà ọ̀hún. Àwọ̀ iná rẹ̀ ń darí oru láti Òòrùn.
Sísọ oríi pápá àti ibùdó èrò tó wò'ran di tútù nílò àwọn ọ̀nà-àbáyọ tuntun. Ẹ jẹ́ ka wo inú rẹ̀.
Lọ́jọ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ èrò ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) ni yóò wà ní ibùdó èrò tó ń wò'ran tí oru àti omi yóò máa jáde lára wọn.
Oru tó ń mú ní Qatar àti oru tó ń jáde níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò níló ètò amú-àyíká-tutù tó péye.
Atẹ́gùn tútù yóò máa fẹ́ sí àwọn èrò tó nífẹ̀ẹ́ eré bọ́ọ̀lù láti abẹ́ ìjókòó wọn ní ibùdó èrò.
Àwọn nọ́zù kéékèèké tó ń ṣe bíi ẹnu omi iléèwẹ̀ ìgbàlódé yóò jẹ́ kí afẹ́fẹ́ bo àwọn èrò tó ń wò'ran.
Afẹ́fẹ́ ọ̀hún yóò máa fẹ́ lẹ́sọ̀ ni yàtọ̀ sí fífẹ́ lójú kan náà gẹ́gẹ́ bíi ọyẹ́ inú bàálù.
Èyí yóò ṣe àwọn èrò lóore, ṣùgbọ́n àwọn agbábọ́ọ̀lù tó wà lóríi pápá ńkọ́?
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ìgbàlódé lè sáré tó ju kilómità mẹ́wàá lọ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan ti wọn yóò sì láàgùn tó tó lítà mẹ́ta nítorí náà wọn nílò láti mú ara tutù àti láti ní omi nínú ara.
Nínú àyíká Qatar tó ní ọ̀gìnìǹtìn yóò nira fun oógùn láti gbẹ, ara sì lè gbònà jù èyí tó lè mú kí ó oru jẹ́ kó rẹ ènìyàn.
Fún ìdíje ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àgbáyé Qatar wọn yóò máa gbé afẹ́fẹ́ tó tutù wọ inúu pápá ìṣeré lọ́nà nọ́zù ńlá nítorí kí orí pápá lè tutù.
Onímọ̀ nípa ẹ̀rọ ọlọ́yẹ́ tó ṣe ètò ọ̀hún, Ọ̀mọ̀wé Said Abdul Ghani, sọ pé ọ̀nà tí àwọn ihò afẹ́fẹ́ ń bá jade kọjú sí àti ibi tí afẹ́fẹ́ tútù náà ń wọlẹ̀ sí kò ní jẹ́ kí àwọn agbábọ́ọ̀lù gbọ́ pé atẹ́gùn ń fẹ́.
Èyí yóò ṣe òkùnfà afẹ́fẹ́ tó tutù níwọ̀nba nínú pápá ìṣeré, tí kò ní ga ju mítà méjì lọ láti ilẹ̀ àbí ibùdó èrò,yàtọ̀ sí kí wọ́n fẹ́ ọyẹ́ sí òkè aṣálẹ̀. Kí ló wá máa wá sẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
Bí afẹ́fẹ́ tútù ọ̀hún bá ṣe ń gbóná, ni àwọn fáánù kan yóò máa fàá jáde.
Lẹ́yìn náà ni wọn yóò ṣẹ́ afẹ́fẹ́ náà tí wọ́n yóò sì tún sọọ́ di tútù tí wọ́n yóò sì dáa padà sí inú pápá ìṣeré.
Báwo ni wọ́n ṣe ń sọ afẹ́fẹ́ náà di tútù kí ará lè dẹ àwọn èèyàn nínú pápá ìṣeré náà. Ẹ jẹ́ ká fi ojú sùnùkùn wòó.
Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà láti sọ afẹ́fẹ́ gbígbóná náà di tútú ni gbígbé afẹ́fẹ́ ọ̀hún gba inú páìpù tó ní omi tútù ní gbogbo igun pápá ìṣeré ọ̀hún.
Tí omi tútù náà bá ti fa oru, wọn yóò tarí rẹ̀ sínú táńkì kan tó lè gba lítà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000). Ibi tí tánkì ọ̀hún wà jìnà tó kìlómità mẹ́ta. Ibẹ̀ ni wọ́n yóò ti tún sọọ́ di tútù fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọjọ́ kejì.
Ohun tó ń fún ètò amú-àyíká-tutù ọ̀ún ní iná ni ẹ̀rọ iná Òòrùn (solar plant) kan tó tó ọgọ́rin (80) kilómità sí olú ìlú Qatar, Doha.
Sísọ oríi pápá àti ibùdó èrò tó wò'ran di tútù nílò àwọn ọ̀nà-àbáyọ tuntun. Ẹ jẹ́ ka wo inú rẹ̀.
Lọ́jọ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ èrò ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) ni yóò wà ní ibùdó èrò tó ń wò'ran tí oru àti omi yóò máa jáde lára wọn.
Oru tó ń mú ní Qatar àti oru tó ń jáde níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò níló ètò amú-àyíká-tutù tó péye.
Atẹ́gùn tútù yóò máa fẹ́ sí àwọn èrò tó nífẹ̀ẹ́ eré bọ́ọ̀lù láti abẹ́ ìjókòó wọn ní ibùdó èrò.
Àwọn nọ́zù kéékèèké tó ń ṣe bíi ẹnu omi iléèwẹ̀ ìgbàlódé yóò jẹ́ kí afẹ́fẹ́ bo àwọn èrò tó ń wò'ran.
Afẹ́fẹ́ ọ̀hún yóò máa fẹ́ lẹ́sọ̀ ni yàtọ̀ sí fífẹ́ lójú kan náà gẹ́gẹ́ bíi ọyẹ́ inú bàálù.
Èyí yóò ṣe àwọn èrò lóore, ṣùgbọ́n àwọn agbábọ́ọ̀lù tó wà lóríi pápá ńkọ́?
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ìgbàlódé lè sáré tó ju kilómità mẹ́wàá lọ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan ti wọn yóò sì láàgùn tó tó lítà mẹ́ta nítorí náà wọn nílò láti mú ara tutù àti láti ní omi nínú ara.
Nínú àyíká Qatar tó ní ọ̀gìnìǹtìn yóò nira fun oógùn láti gbẹ, ara sì lè gbònà jù èyí tó lè mú kí ó oru jẹ́ kó rẹ ènìyàn.
Fún ìdíje ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àgbáyé Qatar wọn yóò máa gbé afẹ́fẹ́ tó tutù wọ inúu pápá ìṣeré lọ́nà nọ́zù ńlá nítorí kí orí pápá lè tutù.
Onímọ̀ nípa ẹ̀rọ ọlọ́yẹ́ tó ṣe ètò ọ̀hún, Ọ̀mọ̀wé Said Abdul Ghani, sọ pé ọ̀nà tí àwọn ihò afẹ́fẹ́ ń bá jade kọjú sí àti ibi tí afẹ́fẹ́ tútù náà ń wọlẹ̀ sí kò ní jẹ́ kí àwọn agbábọ́ọ̀lù gbọ́ pé atẹ́gùn ń fẹ́.
Èyí yóò ṣe òkùnfà afẹ́fẹ́ tó tutù níwọ̀nba nínú pápá ìṣeré, tí kò ní ga ju mítà méjì lọ láti ilẹ̀ àbí ibùdó èrò,yàtọ̀ sí kí wọ́n fẹ́ ọyẹ́ sí òkè aṣálẹ̀. Kí ló wá máa wá sẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
Bí afẹ́fẹ́ tútù ọ̀hún bá ṣe ń gbóná, ni àwọn fáánù kan yóò máa fàá jáde.
Lẹ́yìn náà ni wọn yóò ṣẹ́ afẹ́fẹ́ náà tí wọ́n yóò sì tún sọọ́ di tútù tí wọ́n yóò sì dáa padà sí inú pápá ìṣeré.
Tí omi tútù náà bá ti fa oru, wọn yóò tarí rẹ̀ sínú táńkì kan tó lè gba lítà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000). Ibi tí tánkì ọ̀hún wà jìnà tó kìlómità mẹ́ta. Ibẹ̀ ni wọ́n yóò ti tún sọọ́ di tútù fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọjọ́ kejì.
Ohun tó ń fún ètò amú-àyíká-tutù ọ̀ún ní iná ni ẹ̀rọ iná Òòrùn (solar plant) kan tó tó ọgọ́rin (80) kilómità sí olú ìlú Qatar, Doha.
Dr Cool
Ọkùnrin tó ṣe ètò ọ̀hún, Dr Saud Abdul Ghani, sọ fún BBC pé Qatar fẹ́ ṣe ohun mánigbàgbé tí yóò máa ṣe àǹfàání fún orílẹ̀èdè náà lẹ́yìn tí àwọn agbábọ́ọ̀lù bá lọ sí ilé tán.
Ó sọ pé ìwádìí tó tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló ti lọ sí inú ètò ọ̀hún tó pè ní "thermal comfort", tó pèsè àyíká tó dẹrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn eléré ìdárayá àti àwọn olólùfẹ wọn nínú ìdíje World Athletics Championships tí wọ́n ṣe ní Qatar ní ọdún 2019 pèsè òye nípa ètò ọ̀hún tí yóò ṣe àwọn àlejò àti àwọn agbábọ́ọ̀lù ní àǹfààní nígbà ìdíje ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àgbáyé.
Èrò agbábọ́ọ̀lù
BBC kàn sí Hajar Saleh, tó ń gbá ẹ̀yìn fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù obìnrin orílẹ̀èdè Qatar tó sì ti ń gbá bọ́ọ̀lù láti ìgbà tó ti di ọmọ ọdún mọ́kànlá (11). Ó mọ̀ nípa ìdojúkọ tó wà nínú gbígbá bọ́ọ̀lù ní àyíká tó le. Ó sọ pé ọ̀gìnìǹtìn ni ìdọjúkọ tó lágbára jù.
Oru ti mọ́ wa lára, ṣùgbọ́n tí o bá da oru pọ̀ mọ́ ọ̀gìnìǹtìn, nǹkan yóò ṣòro síi. Hajar Saleh
Hajar ti ní ìrírí gbígbá bọ́ọ̀lù nínúu méjì lára àwọn pápá ìṣeré tuntun ọ̀hún tó ní ètò amú-àyíká-tutù, pápá iṣeré Khalifa àti pápá ìṣeré Educationa City.
Ó ní ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ pọ̀, pàá-pàá tí èèyàn bá ń gbá bọ́ọ̀lù nínú oṣù kẹfà, ọ̀kan lára àwọn oṣù tó gbóná jù ní Qatar.
Ṣé ètò ọ̀hún ní àlòpẹ́?
Àwọn tó ń ṣètò Qatar 2022 ṣe ìlérí pé ètò amú-àyíká-tutù ọ̀hún kó ní ṣe okùnfà àlékún afẹ́fẹ́ tó léwu fún àyíká (greenhouse gass emmission) nítorí pé iná tó ń lò ń wá láti ẹ̀rọ iná Òòrùn tuntun orílẹ̀èdè náà.
Ṣùgbọ́n èrò àti ríi pé ìdíje ọ̀hún kò ṣe okùnfà afẹ́fẹ́ẹ tó ba àyíká jẹ́ afojúsùn tó lágbára.
Iye èéfin 'carbon' tó jẹyọ níigbà tí wan kọ́ àwọn pápá ìṣeré náà jẹ́ ìdá àádọ́rùún nínú ọ̀gọ́rùnún (90%) nínú gbogbo èéfín 'carbon' tó tú sí àyíká, níbi tí èéfin gáàssì tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin (800,000) ti tú sí àyíká. Èyí jẹ́ irú èéfín tí yóò jáde bí èèyàn bá wa mótò káàkiri àgbáyé nígbà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rọ ìṣirò àjọ tó ń dáàbò bo àyíká l'Amẹrika ṣe sọ.
Bí èèyàn bá wòye kọjá àwọn pápá ìṣeré ọ̀hún, ipa tí ìrìnàjò lọ sí ìdíje bọ́ọ̀lù àgbáyé kó nínúẹ̀ wà, àti ti àwọn bàálù tó ń gbé àwọn fáànù lọ sí Qatar.
Àjọ Fifa sọ pé nítorí pé àwọn pápá ìṣeré tí wọ́n yóò ti gbá ìdíje bọ́ọ̀lù àgbáyé kò jìnà sí ara wọn, èéfín gáàsì tí ìrìnàjò nínú Qatar nígbà ìdìje ọ̀hún kò ní tó ìdá kan ìdá mẹ́ta ti ìdíje Russia 2018.
Àwọn ìlérí èéfín tó ba àyíká jẹ́ ti Qatar dá lóríi kí wọ́n dín èéfín tó lè jáde kù gẹ́gẹ́ bíi ohun tí wọ́n yóò fi dí èéfín tó ti jáde.
Níbáyìí ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti rí ṣe kò tíì hàn. Fifa sọ pé àwọn ń lo oríṣìríṣì ìmọ̀ ẹ̀rọ láti ṣe ìtanràn fún àwọn èéfín tí wọ́n tú sí àyíká nígbà ídíje bọ́ọ̀lù àgbáyé, bíi ṣíṣọ́ iná lò, ilẹ̀ kíkọ́, lílo iná tó lè dọ̀tun àti igi gbígbìn. Ṣùgbọ́n a kò lè fi ìdí ohun tí wọn yóò padà ṣe àmúlò múlẹ̀.
Irú àwọn ètò yìí lè tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí wọ́n tó di ṣíṣe. Ìwádìí BBC fi hàn pé àwọn igi kan tí wọ́n ní wọ́n gbìn fún ìtanran èéfín kò kúrò lóríi ìwé tí wan kọọ́ sí.
Nítorí náà yóò pẹ́ díẹ̀ ká tó lè sọ pé bọ́yá Qatar rí ìlérí rẹ̀ mú ṣe nípa dídín èéfín kù àbí àròyé lásán ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa dídáàbò bo àyíká.
Orílẹ̀èdè náà ń kojú òkò ọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ọmọnìyàn àwọn àjòjí òṣìṣẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n tí wọ́n kọ́ àwọn pápá ìṣeré àti bí ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣe kú tí àwọn kan sì farapa. Wọ́n tún ti fi ẹ̀sùn kan oríẹ̀èdè náà nípa ìfipá mú'yàn ṣiṣẹ́, iṣẹ́ àṣe féè kú, ilé tí kò dára, jíjẹ owó òṣìṣẹ́ àti gbígba ìwé ìrìnà (passport) lọ́wọ́ wọn.
Ìjọba Qatar sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, ó sì sọ pé láti ọdún 2017 ni àwọn ti fi ètò lélẹ̀ láti dáàbò bo àwọn aàjèjì tó wá ṣiṣẹ́ kí wọ́n má máa ṣe iṣẹ́ nínú Òòrùn, dín iye wákàtyí tí wọ́n ń fi ń ṣiṣẹ́ kù àti láti mú ìdẹ̀rùn bá ibi tí wọ́n ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ọdún 2021, àwọn àádọ́ta (50) òṣìsẹ́ kú nígbà tí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) farapa ní Qatar nínú àwọn tó ń kọ́ ibi tí wọn yóò ti gbá bọ́ọ̀lù ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé, gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí ájọ iṣẹ́ àgbáyé (ILO) rí ṣe sọ. Eléyìí jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n yóò ti máa ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ orílẹ̀èdè náà.
Àwọn tó ṣe iṣẹ́ yìí
Johannes Dell, Leoni Robertson Sara Fayyad , Mohammad Hamdar àti Dominic Bailey lọ kọọ́ tó ṣì ṣeé
Maryam Nikan àti Gerry Fletcher ló tòó
Kaveri Biswass àti Adam Allen ló ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀
Sally Morales ni alákóso
Ọ̀jọ̀gbọ́n Gareme Maidment ti fásitì London Southbank ni oluùdámọ̀rọ̀n
orísun àwòrán: Getty Images, Hum3d, Hajar Saleh
Ẹ lè nífẹ́ sí àwọn ìròyìn yìí
Ati 450 Itọju Ikẹkọ Ti ara Koko Koko-ọrọ Awọn ọna-aje Awọn ọna Ede Awọn irinṣẹ Nkan Iranlọwọ Wa Indian Indian Internationalization Agbara Agbara. Aṣẹṣẹ dabi pe o ra, laisi itupalẹ. Ushki dabi ẹni pe o n ṣe ipinfunni itọsọna itumọ idanimọ lọwọlọwọ itumọ Amitkumar Sunat ni anfani lati yan itọnisọna eniyan
Nullification ti fẹrẹ pari, ṣugbọn a le pese alaye olumulo. Ṣugbọn ibaraẹnisọrọ ti o pari ti a ko mulẹ ko le fọ, ṣugbọn awọn itọnisọna le ni ilọsiwaju. Akọkọ ni lati ṣetọju agbaye bi awujọ. Ede ni ede ti awujọ.
World Cup 2022: Báwo ni Qatar ṣe hùwà sí àwọn òṣìṣẹ́ pápá ìṣeré? (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì)
Ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ti Qatar 2022: Bí àwọn ìfẹsẹ̀wọnṣẹ̀ yóò ṣe lọ (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì)
Bí wọ́n ṣe ń fi igi gbígbìn dáàbò bo àyíká (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì)