Core include appears below:
Báwo làwọn èèyan lágbàáyé yóò ṣe dẹ́kun lílo epo tó ti mọ̀ wọn lára tó sì n fa àyípadà ojù ọjọ́
Idahun si ibeere yii wa lapo rẹ
Awọn eroja pataki- ti wọn n lo fun foonu wa - wulo fun awọn nnkan agbara ti ko ni i yọ wa lẹnu ti a ba n lo wọn, awọn bii agbara iji to n di ina mọnamọna, awọn batiri to jẹ oorun ni wọn n lo lati tanna fun wa nilee wa, ti wọn si tun wulo fun igbokegbodo ọkọ.
Iwọ naa wo foonu rẹ lọwọ isalẹ ko o wo iru eroja agbara to n jẹ ko ṣiṣẹ.
O ṣee ṣe keeyan ri gbogbo eelo to so foonu rẹ ro, awọn bii oju foonu naa, kinni kekere ti wọn n pe ni micro chips to n gba gbogbo nnkan sori foonu ọhun, awọn waya to gbe foonu ro pẹlu batiri inu rẹ.
Ti o ba tu foonu rẹ palẹ, ohun to o maa ri ree.
Eyi lawọn eroja to gbe foonu ro. Nicklel ta a sọ lẹẹkan wa ninu batiri, Lithium ati Cobalt.
Awọn eroja yii ṣe pataki lati jẹ kawọn ọkọ wa to n lo ina ṣiṣẹ, wọn wulo fun ile atawọn ọfiisi wa, wọn si le ran wa lọwọ lati kapa afẹfẹ buruku ta a fẹẹ ko ti kasẹ nilẹ nigba ti yoo ba fi di ọdun 2030.
Awọn waya to n mu foonu ṣiṣẹ, atẹ waya ati batiri la ṣafihan rẹ yii.
Nikẹẹli wa ninu awọn ẹya foonu yooku naa. Bakan naa lo ṣe wa ninu awọn nnkan eelo mi-in ta a n lo pẹlu titi to fi mọ awọn irinṣẹ eto ilera.
Batiri inu foonu rẹ la ṣafihan rẹ yii
Lithium jẹ eroja kan ti wọn maa n lo lati mu ara eeyan balẹ, wọn maa n lo o lati tọju ailera to ba jẹ mọ ọpọlọ.
Batiri inu foonu rẹ la ṣafihan rẹ yii
Eroja Cobalt ni tiẹ, awọn batiri ta a tun le ro lagbara pada iyẹn ‘rechargeable battery’ ni wọn maa n saba lo o fun. O si maa n wa ninu awọn ẹṣọ ara ta a n lo naa.
Ki lo de ta a fi mu lele lori batiiri? Nitori awọn eroja mẹta yii ṣe pataki fawọn orilẹ ede lati koju iṣoro ayipada oju ọjọ ni
Awọn batiiri to wa ninu mọto to n lo ina mọnamọna ṣe pataki gidi, awọn eeyan si maa n beere wọn pupọ nitori iwulo wọn.
Lọdun 2020, eyọ kan ninu mọto mẹẹẹdọgbọn ti wọn ta kaakiri agbaye lo n lo ina mọnamọna, gẹgẹ bi ajọ International Energy Agency (IEA) ṣe wi. Lọdun yii, o ti gbaradi lati di marun-un ninu ẹyọkan.
Gẹgẹ bi IEA ṣe wi, awọn mọto to n lo ina mọnamọna yii maa n mọ nilọpo mẹrin tabi ju bẹẹ lọ ju tawọn to n lo epo lọ. Bi wọn ba n ro wọn lagbara lati ara oorun ati nnkan ọgbin nigba mi-in, eyi ti wọn n pe ni green source.
Awọn ilana iro-nnkan- lagbara toyinbo n pe ni green technologies bii atẹ oorun, mọto to n lo ina mọnamọna atawọn to n sọ agbara iji di lilo jẹ awọn eroja ta a nilo gidi.
Ti yoo Ba fi di ogun ọdun si asiko ta a wa yii, awọn mọto to n lo ina mọnamọna yoo ti pọ gidi, bẹẹ naa si la o ṣe maa tọju agbara eelo rẹ fun lilo (grid storage)
Ẹ jẹ ka wo bawọn eeyan ṣe n beere awọn eroja pataki yii to
Bawo ni nnkan yoo ṣe yipada pẹlu ba a ṣe n fẹ afẹfẹ to mọ ti ko labawọn
Odiwọn iwakusa yii jẹ eyi ta a nilo( Ki i ṣe pe a pe e ni rẹgi ti yoo jẹ)
Bi wọn ṣe lo Nickel to kaakiri agbaye ree lọdun to kọja, 3, 200 kilotones, iyẹn ẹgbẹrun mẹta ati igba kilotone (iwọn mọto milọnu mẹta ati ẹgbẹrun meji niyẹn)
Lati ri afẹfẹ atura ti ko si ijamba eefin ninu rẹ ṣe ni 2030 ta n fojusun, a niloo ẹgbẹrun marun-un ati ẹẹdẹgbẹrin kilotone eroja Nickel (5,700 kilotones).
Ṣugbọn odiwọn Nickel to wa lasiko yii ko ju ẹgbẹrun mẹrin ati ogoje lọ( 4, 140 kilotones). Eyi to jinna si iye ta a nilo lati ni afẹfẹ alaafia lọdun 2030.
Ẹ jẹ ka wo Litiọmu ati Cobalt naa wo.
Litiọọmu ọgọrun-un kan ati mẹrindinlaadọta (146Kilotones) lawọn eeyan beere fun ni 2022, wọn ni yoo mu afẹfẹ alaafia wa ni 2030. Ọgọrun meje ati meji kilotone (702 kilotones) ni wọn lo yẹ ko wa nita ni 2030, kilotoonu igba naa yoo si jẹ 420, iyẹn irinwo-le-logun.
Nigba ti yoo ba fi di 2030, a gbọdọ ṣafikun litiọomu ta a ba fẹẹ din bi oju ọjọ yoo ṣe mooru lagbaaye ku si odiwọn 1.5C
Cobalt: ni 2022,200 Kt, iyẹn igba kilotoonu eroja Cobalt lawọn eeyan beerer fun, wọn loun naa yoo mu afẹfẹ alaafia wa ni 2030,ọọdunrun le mẹrindinlaaadọta kilotone (346 Kt) ni yoo ni. Iye rẹ ti wọn si fojusun pe yoo wa ni 2030 jẹ ọodunrunle mẹrinla (314).
Gẹgẹ bo ṣe ri fun Litiọọmu, a gbọdọ ri i daju pe a ṣafikun iye Cobalt lati le din baye ṣe maa mooru ku si 1.5C ta a sọ
Ẹ jẹ ka wo ibi ti wọn ti n wakusa awọn nnkan eelo alumọni yii lagbaaye
Ni 2022,Indonesia Philippines ati Russia pese ida meji ninu mẹta Nickel ti gbogbo agbaye lo
Australia, Chile ati China wakusa ida mọkanlelaadọrun-un (91%) litiọmu lagbaaye.
Orilẹ-ede Congo, Australia ati Indonesia wakusa cobalt ida mejilelọgọrin (82%) fun lilo agbaaye.
Cobalt to n ti Congo wa, ida mẹrinlelaadọrin ni (74%), Nickel Indonesia jẹ ida mọkandinlaaadọta (49%), Litiọmu fun Australia si jẹ ida mẹtadinlaaadọta (47%).
Iwakusa awọn nnkan eelo ti wọn wulo pupọ yii ṣe ọwọ awọn orilẹ-ede kan. Eyi lawọn to n pese awọn nnkan wọyi ju ati ohun ti kaluku wọn n pese gan-an
Nibo ni wọn ti n po awọn eroja yii pọ?
Awọn ibi ti wọn ti n pọ awọn eroja wọnyi tilẹ tun wọpọ ju ibi ti wọn ti n wakusa wọn lọ.
China, Cobalt, ida mẹrinlelaadọrin (74%), Luthium; ida marundinlaadọrin (65%), Indonesia, ida mẹtalelogoji (43%).
Orilẹ-ede China n ṣe pupọ ninu lithium ati cobalt, nigba ti Indonesia n pese nickel to pọju lọ.
China, ida mẹrinlelaadọrin Cobalt, (74%) lithium tiwón jẹ ida marundinlaadọrin (65%), nikckel si jẹ ida mẹtadinlogun (17%).
Orilẹ-ede China tun n pese awọn nnkan eelo ti ko fi bẹẹ wọpọ loke eepẹ, to si jẹ pe wọn lo awọn nnkan naa fun imọ ẹrọ igbalode ni.
Itan ti jẹ ko ye wa pe ewu n bẹ loko Lọngẹ ta a ba kuna lati dari awọn nnkan eelo pataki yii sibi to yẹ.
Tim Gould, IEA.
Ni Chile, irinṣẹ iwakusa kan a maa gbe eroja ti wọn n ri lati ara iyọ
Ibudo iwakusa Lithium ni Chile.
Ki ni awọn ipenija to n koju ipese awọn eroja pataki yii?
O le to ọdun mẹẹẹdogun tabi ju bẹẹ lọ ki ibudo iwakusa too ṣee ṣe, bẹẹ a ko ni ju ọdun meje lọ ti ọdun 2030 yoo fi de.
Obinrin kan n ṣiṣẹ nibudo iwakusa kan ni DR Congo, ko si sohun kan to maye dẹrun nibudo iṣẹ naa.
Ibudo iwakusa ni Congo
Bi wọn ba ṣawari ibudo tuntun, awọn ohun amayedẹrun lati dẹbẹ bii oju ọna to daa le ma si, ti ati ṣe ohunkohun nibẹ yoo si ṣoro.
Aabo to peye le ma si nibudo iwakusa tuntun, o si yẹ ki ajọsọ wa pẹlu awọn alakooso agbegbe naa ki iṣẹ iwakusa ọhun le jẹ ti otitọ ati ododo.
Ni Congo, iwakusa too gbooro si ti jẹ ki wọn le ọpọ eeyan jade pẹlu ipa ri laduugbo wọn, nitori Cobalt ati Copper ti wọn fẹẹ wa. Wón fiya jẹ awọn eeyan naa pupọ wọn si tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ gidi.
Ajọ to n ri si iforijini.
B’ọjọ ṣe n gori ọjọ, a maa nilo lati maa sọ batiri di nnkan eelo mi-in ti yoo tun ṣee lo.
Awọn onimọ sayẹnsi gbagbọ pe pupọ ninu awọn batiri ọkọ to n lo ina lo yẹ kawọn to n lo wọn paarọ wọn laarin ogun ọdun ti wọn ti n lo wọn.
Awọn oniṣẹ iwadii lati Yunifasiti Birmingham ni UK sọ peko to idaji ninu ohun ti wọn fi n ṣe batiri to jẹ pe eeyan le sọ di eroja mi-in lọwọ yii.
Ṣugbọn wọn ni ida ọgọrin rẹ le ṣee ṣe bẹẹ laarin ogun ọdun sigba ta a wa yii.
A ni lati ronu ona mi-in nipa ba a ṣe n ṣe awọn batiri yii, ko le baa rọrun lati sọ wọn di nnkan eelo mi-in ti yoo tun wulo.
Ọjọgbọn Paul Anderson lati Yunifasiti Birmingham, ni UK.
Pẹlu iye batiri ta a n pese,eeyan o le ri nnkan kan ṣe si i. Ko si nnkan eelo to to lasiko yii lati pese gbogbo awọn batiri ta a n gbero lati ṣe.
Ọjọgbọn Paul Anderson, ti Yunifasiti Birmingham ni UK.
...there we go.