Ìdìtẹ̀gbajọba tó kẹ́sẹ járí tó tó àádóje ló ti wáyé ní orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlógójì ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti ọdún 1952 nígbà tí Ọba Farouk ti Egypt di olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tí bwọ́n kọ́kọ́ yọ nípò.
Àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba tó kẹ́sẹ járí mẹ́jọ ló wáyé láàárín ọdún mẹ́ta nílẹ̀ Adúláwọ̀. Ìdìtẹ̀gbàjọba ọ̀tun tó ń wáyé látọwọ́ àwọn ológun lásìkò yìí ló tún bẹ̀rẹ̀ nígbà tó ti ń wawọ́ bolẹ̀ ní ọdún 2020 lẹ́yìn tó ti peléke ní ọdún 1970.
Ọ̀pọ̀ àwọn olórí tó fipá gbàjọba ni wọ́n lo ọ̀pọ̀ ọdún lórí ipò nígbà tí wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ àwọn míì láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n gbàjọba.
Ààrẹ Equatorial Guinea,Teodoro Obiang Nguema gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí wà nípò ààrẹ fún ọdún mẹ́rìnlélógójì láti ìgbà tó gbàjọba lọ́dún 1979.
Òun ni olórí tó ti wà nípò fún ìgbà tó pẹ́ jùlọ nílẹ̀ Áfíríkà.
Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ní ẹkùn yìí ni àwọn ológun ti gbàjọba níbẹ̀ rí. Àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní ẹkùn ní kò pẹ́ yìí ló wáyé ní Niger àti Gabon ní 2023.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀gá nílé iṣẹ́ ológun ni wọ́n gbàjọba ní Mali lọ́dún 2020 àti 2021, ní Chad, Guinea àti Sudan lọ́dún 2021. Ìdìtẹ̀gbàjọba méjì ló wáyé ní Burkina Faso lọ́dún 2022. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yìí ló jẹ́ orílẹ̀ èdè tílẹ̀ Faransé músìn yàtọ̀ sí Sudan nìkan.
Láti ọdún 2000, ìdá mẹ́ta (mọ́kàndínlógún nínú mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n) nínú àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé nílẹ̀ Adúláwọ̀ ló ti wáyé ní àwọn orílẹ̀ èdè táwọn Faransé músìn. Èyí ló ń fa ìbéèrè pé ṣe ipá Faransé ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Adúláwọ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ní ìwọ̀ oòrùn àti ààrin gbùngbùn Áfíríkà ni ìdìtẹ̀gbàjọba ti wáyé níbẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ìdajì orílẹ̀ èdè mẹ́tàdínlógún tí ó kéré tán ìdìtẹ̀gbàjọba mẹ́rin kẹ́sẹ járí níbẹ̀ ló wà ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà.
Burkina Faso ní ìdìtẹ̀gbàjọba tó kẹ́sẹ járí jùlọ nílẹ̀ Adúláwọ̀ ti wáyé pẹ̀lú ìdìtẹ̀gbàjọba mẹ́jọ, Sierra Leone àti Uganda ló tẹ̀le pẹ̀lú méje méje.
Ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà, pàápàá ní ìlà oòrùn àti gúúsù Áfíríkà ni ìdìtẹ̀gbàjọba kò kẹ́sẹ járí níbẹ̀.
Lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ́dún 2024, Ibrahim Traoré ni ààrẹ tó ń ṣèjọba lọ́wọ́ tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ ní àgbáyé. Ó di olórí orílẹ̀ èdè Burkina Faso lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022 nígbà tí wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ Paul-Henri Sandaogo Damiba.
Bíi ìdá àádọ́rùn-ún àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé ló jẹ́ látọwọ́ àwọn ológun, àwọn ajaguntà ló tẹ̀lé pẹ̀lú ìdá mẹ́rin. Irú àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba míì wáyé látọwọ́ ìwọ́de aráàlú, agbára àwọn amúnisín, àwọn ọmọ ogun ọlọ́tẹ̀ àti ìdìtẹ̀gbàjọba ààfin.
Ọ̀pọ̀ àwọn olórí orílẹ̀ èdè tí wọ́n gbàjọba nípa ìdìtẹ̀gbàjọba ni wọ́n máa ń yọ kúrò nípò tàbí kí wọ́n pawọ́n.
Ní ọdún 1972, Ọ̀gágun Ignatius Kutu Acheampong ṣaájú ìdìtẹ̀gbàjọba tí kò ní ìtàjẹ̀sílẹ̀ rárá láti gbàjọba lọ́wọ́ olóòtú ìjọba Ghana tí wọ́n dìbò yàn, Dókítà Kofi Busia. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n yọ òun náà nípò pẹ̀lú ìd]itẹ̀gbàjọba ààfin, tí wọ́n sì fẹ̀yìn rẹ̀ ti àgbá ní nǹkan bíi ọdún kan sígbà náà.
Thomas Sankara di ààrẹ Burkina Faso lọ́dún 1983 níbà tí wọ́n ṣe ìdìtẹ̀gbàjọba kan lórúkọ rẹ̀ lásìkò tí wọ́n fi òfin mú sílé. Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹwàá, ọdún 1987 ni ikọ̀ ọmọ ogun kan pa Sankara níbi ìdìtẹ̀gbàjọba tí Blaise Compaoré tó gbapò ààrẹ lẹ́yìn rẹ̀ ṣaájú.
Gaafar Nimeiry gbàjọba lọ́wọ́ olórí orílẹ̀ èdè Sudan, Ismail al-Azhari lọ́dún 1969 láti di olórí ikọ̀ ọmọ ogun àti ààrẹ kó tó di pé wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ òun náà lọ́dún 1985.
Jean-Baptiste gbàjọba lọ́wọ́ ààrẹ Burundi, Michel Micombero lọ́dún 1976 tó sì gba ipò náà. Ọdún mọ́kànlá lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ òun náà tí wọ́n sì le kúrò nílùú.
Omar al-Bashir gba agbára lọ́dún 1989 nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun ilẹ̀ Sudan tó sì ṣaájú ikọ̀ ọmọ ogún láti fipá gbàjọba lọ́wọ́ ìjọba tí wọ́n dìbò yàn. Ó ṣe olórí orílẹ̀ èdè Sudan láti ọdún 1989 títí di ọdún 2019 tí wọ́n fipá gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀.
François Bozizé Yangouvonda gbàjọba lọ́dún 2003 láti ààrẹ Central African Republic kẹfà. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá ni wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀.
Fífi sínú ẹbí kan náà
Gbígba agbára jẹ́ àṣà ìdílé ní àwọn orílẹ̀ èdè kan. Ààrẹ Equatorial Guinea, Teodoro Obiang Nguema Mbasogo gbàjọba lọ́wọ́ ìbátan rẹ̀, Francisco Macías Nguema nínú ìdìtẹ̀gbàjọba tó la ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ lọ́dún 1979. Títí di ọdún 2024, Teodoro ni olórí orílẹ̀ èdè kejì tó ti pẹ́ lórí ipò láì kìí ṣe ọba.
Laurent Kabila gbàjọja lọ́wọ́ ààrẹ Mobutu Sese Seko lọ́dún 1997 láti di ààrẹ DR Congo kẹta. Ọmọ rẹ̀, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ló di ààrẹ lẹ́yìn tí ọ̀kan lára àwọn ẹṣọ́ rẹ̀ ṣekúpa á.