Test Page
Pese Awọn alaṣẹ Ẹlẹda ni kiakia Rọle si Awọn ọna Iyọlẹnu Eyikeyi ti Ilu India ṣafikun Awọn anfani Agbaye Ni Agbegbe Ayikaṣe Nipa fifun Awọn akiyesi Ọdun Ọdun Forex Lati Ṣẹda Ọfiisi, Ifiranṣẹ Koko Ipo Ipo Rẹ
Alaye ore-aye, aaye wọn ti wo, ijiroro, eto, ọja, bbl, awọn ibi-afẹde ipo-akọkọ jẹ kanna. Ifunni itọsọna itọsọna rira ni a sọ fun. Ni bayi ọrọ koko ominira Gẹẹsi ko sọ taara nipasẹ abala naa. Jaane Dishame Igbimọ Ijumọsọrọ Iṣeduro Itagiri Agbaye Tiaja Ẹgbẹ pataki ṣugbọn
Ileeṣẹ BBC lo ti fi orukọ obirin ọgọrun to n ṣe moriya fawọn obirin ẹgbẹ wọn ti wọn si tun gbajugbaja julọ lagbaye lede fun ọdun 2023.
Lara awọn ọgọrun yii ni a ti ri aya aarẹ ilẹ America tẹlẹ ri Michelle Obama ati agbẹjọro to n ja fẹtọ ọmọniyan Amal Clooney. Awọn yoku ni obinrin to mọ bọọlu gba julọ lagbaye Aitana Bonmati, onimọ nipa AI Timnit Gebru, ajafẹtọ awọn obirin Gloria Steinem, oṣere sinima nilẹ America Ferrera ati oniṣowo aṣaraloge Huda Kattan.
Ninu ọdun ti iroyin nipa oorun to gbona jọjọ, ina ajojotan, ikun omi ati oniruuru ajalu to kolu awọn nkan adayeba gbode kan, akojọpọ orukọ wọnyii saami si awọn obirin to ti n ṣiṣẹ lati pese iranlọwọ fun awọn agbegbe wọn nipa titako ayipada oju ọjọ ati nipa fifi afaramọ ipa rẹ.
Awọn eeyan mejidinlọgbọn to bẹ̀rẹ̀ mímojuto ayika ti wọn ti fi orukọ wọn lede ṣaaju ipade igbimọ gbogboogbo ti orilẹ-ede agbaye lori ọrọ ayipada oju ọjọ 'United Nations Climate Change Conference, COP28' wa ninu akojọpọ yii
A ko to awọn orukọ wọnyii jọ pẹlu ilana kankan
Aṣa ati ẹkọ
Afroze-Numa, Pakistan
Olùtọ́jú àwọn ẹranko
Ọ̀kan lára àwọn olùtọ́jú Wakhi ìkẹyìn, Afroze-Numa ṣe ìtọ́jú àwọn ewúrẹ́ àtàwọn àgùntàn fún bí ọgbọ̀n ọdún.
Lọ́dọ̀ ìyá àti ìyá-ìyá rẹ̀ ló ti kọ òwò náà, ó wà lára àwọn tó ṣì ń ṣòwò tó ti ń lọ sóko ìparun ní ẹkùn Shimshal valley ní Palestine.
Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń kó àwọn ẹranko náà jẹ̀ lọ ibi tó jìn ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́rìndínlógún, níbi tí wọ́n ti máa ń fún wàrà wọn láti fi gba pààrọ̀, tí àwọn ẹranko náà yóò sì jẹun.
Òwò yìí ti mú ìlọsíwájú bá ìlú wọn àti pé ó jẹ́ kí wọ́n lè pèsè ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ wọn. Afroze-Numa ṣì máa ń rántí pé òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ ra bàtà ní ìlú wọn.
Hosai Ahmadzai, Afghanistan
atọkun amohunmaworan
Nigba ti Taliban gba ijọba ni oṣu kẹjọ ọdun 2021,Hosai Ahmadzai jẹ ọkan lara awọn akaroyin ni ẹka agbohun safẹfẹ ni Afghanistan.
Kò jawọ nidi iṣẹ rẹ ni Shamshad TV tohun ti atako to n waye lawujọ to wa fun ikopa awọn obinrin lẹka iroyin.
Aimọye olori Taliban lo ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun ṣugbọn kii ṣe gbogbo ibeere lo le bi wọn.
Ahmadzai jẹ onimọ nipa ofin to sì kawe gboye nipa imọ oṣelu. Lati ọdun meje sẹyin lo ti n ṣiṣẹ lẹka iroyin. Ọrọ ẹkọ awọn ọmọbinrin, ti awọn Taliban koro oju si jẹ logun lọpọ
Esi Buobasa, Ghana
Apẹja
Esi Buobasa jẹ ọmọ bibi Fuveme, abule kan ni ilu Ghana tii se ọkan lara awọn ti okun ti wọ lọ. O si mọ akoba nla ti ayipada oju ọjọ mu wa lara pupọ.
Nigba ti okun kun si, ti awọn eeyan ko si fẹ kuro ni agbegbe ti wọn n gbe, oun ati ọkọ rẹ pẹlu awọn ọmọ wọn marun ko lọ si ibomiran.
Buobasa, tii se gbajumọ iya ẹlẹja ni abule rẹ wa da ẹgbẹ kan silẹ pẹlu awọn akẹẹgbẹ rẹ. Afojusun wọn si ni lati seranlọwọ fawọn obinrin apẹja lagbegbe naa nitori bi agbara eti okun se n dunkooko mọ orisun ọrọ aje wọn.
Ẹgbẹ naa, ti ko ni ju ọgọrun ọmọ ẹgbẹ lọ, lo maa n se ipade ni ẹẹkan lọsẹ lori awọn ọrọ to n se akoba fawọn obinrin ati okoowo wọn. Ẹgbẹ naa si da owo fawọn mọlẹbi to se alaini ni abule naa.
A ma n sọ ireti nu lasiko ti ẹkun omi yii ba waye. Iku ti de fun awa ati iran to n bọ.
Esi Buobasa
Chila Kumari Burman, UK
Ayaworan
Ninu isẹ ṣiṣe ni oriṣiriși awọn ọna bii titẹ iwe, yiya aworan, kikub ọda, fifi sori ẹrọ ati fiimu, Chila Kumari Burman n lo iṣẹ rẹ lati jiroro lori awọn ọrọ bii aṣoju, idanimọ akọ, abo ati aṣa.
Ni ọdun yii, ayaworan naa ti ṣe afihan awọn isẹ rẹ ni 'Blackpool Illuminations', ayẹyẹ imọlẹ ti o maa n waye ni UK lati 1879. 'Lollies in Love With Light' jẹ ẹrọ igbalode ti a fi si ara ọkọ ti a fi pin ohun adidun, 'Ice Cream' ti o gbe kalẹ nipase oko owo 'Ice Cream' ti awọn obi rẹ n ṣe.
Ni ọdun 2020, Burman ṣe agbekalẹ tuntun, ni iranti 'Brave New World adorning Tate Britain's façade', ni ibamu pẹlu awọn itọkasi itan aye atijọ India, aṣa olokiki ati ironilagbara fun awọn obinrin.
O gba ami ẹyẹ MBE l'ọdun to kọja.
Paulina Chiziane, Mozambique
onkọwe
Paulina Chiziane ni obirin akọkọ ti yoo tẹ iwe jade lorilẹ-ede Mozambique pẹlu ‘Ballad of Love in the Wind’ ni nkan bii ọdun 1990.
Chiziane dagba nitosi Maputo to jẹ olu-ilu Mozambique nibi to ti kọ ede potoki nile-ẹko aguda kan. O tun kẹkọ nipa ede ni fasiti Eduardo Mondlane amọ ko ṣetan nibẹ.
Oriṣiriṣi ede bii Gẹẹsi, German, ati Spanish ni wọn ti ṣe ẹda awọn iwe rẹ si, to si ti gba ami ẹyẹ loniranran.
Ni aipẹ yii ni o gba ami ẹyẹ Camões ti o jẹ ami ẹyẹ tó lààmì-laaka jùlọ fun awọn onkọwe lede Portuguese ní àgbáyé.
Susanne Etti, Australia
Onimọ nipa irinajo afẹ to fẹsẹrinlẹ
Ọkan lara diẹ ninu awọn onimọ sayẹnsi ni ẹka irinajo afẹ ati oju ọjọ, Susanne Etti lo ni itara nipa lilewaju ẹka naa si ifẹsẹmulẹ ọjọ ọla to duro re.
Isẹ rẹ gẹgẹ bii alakoso to n lapa rere ni ẹka akoso ayika lagbaye ninu ẹgbẹ Intrepid Travel, ẹgbẹ kekere kan to n dokowo ninu irinkerindo lẹka irinajo afẹ, lo ti mu ki ileesẹ naa di akọkọ ti yoo lo sayẹnsi lati mu adinku ba afẹfẹ ti ko dara ti a n mi sinu.
Etti ti kọ iwe kan to n se atọna fawọn atnisọna lẹka okoowo irinajoafẹ, ti wọn nifẹ lati mu adinku ba afẹfẹn ti ko dara ti a n mi sinu, eyi to se gboogi gẹgẹ bi ara ẹka eto afẹ to ni ẹgbẹ to to irinwo niye atawọn ileesẹ kekeke to ti kede pe nnkan ko fararọ ni ẹka ni ẹka oju ọjọ.
Loni, a n ri ọpọlpọ awọn olokoowo to n mọ riri isepataki igbesẹ lori oju ọjọ nipa gbigbe awọn afojusun to se pataki kalẹ eyi ti yoo mu adinku ba ipa ti ayipada oju ọjọ n ni didokowo ninu ohun amusagbara, to si tun n gbajumọ mimu adinku ba afẹfẹ ta n fọn sita fun igba pipẹ.
Susanne Etti
Jannatul Ferdous, Bangladesh
Ida ọgọta nina ida ọgọrun un ara Jannatul Ferdous ni ina ti jo ri. Lẹyin naa lo di ẹni to n ṣe fiimu, to n kọwe to si tun jẹ olupolongo fawọn akanda ẹda.
Ferdous lo da ajọ ajafẹtọọ ọmọniyan ti wọn n pe ni ‘Voice and Views’ silẹ, eyi to n ja fun ẹtọ awọn obinrin ti wọn ti kagbako ina ri.
Ivy ni orukọ ti ọpọ awon ọrẹ ati ẹbi rẹ n pe e. O ti ṣe fiimu marun un to si tun gbe iwe mẹta jade ni eyi to fi n fọn rere nipa awọn eeyan to jẹ akanda ẹda.
Ferdous ka iwe to pọ koda, o ni imọ ijinlẹ ninu litireṣọ ede Oyinbo to si tun gba oye ninu imọ idagbasoke.
Licia Fertz, Italy
Arinrinoge ati alawokọṣe
Ko wọpọ ninu eeyan tọjọ ori wọn jẹ mẹtalelaadọrun-un (93) ti wọn le fọwọ sọya pe awọn ni olutẹle aarun-din-ni-ojilenigba (235,000 followers ) loju opo Instagram awọn, ṣugbọn to ba jẹ ti obinrin to dagba ju ninu awọn ti ẹya ara wọn ṣee mu yangan ni Italy ni, onka yii ko to nnkan rara, bi ẹni to ṣẹṣẹ n mẹyẹ bọ lapo ni tiẹ.
Ojuu Licia Fertz logun Agbaye mejeeji ṣe waye, o farada ibanujẹ ọmọbinrin rẹ to ti pe ẹni ọdun mejidinlọgbon ko too ku, bẹẹ lo tun padanu ọkọ.
Ṣugbọn nigba ti ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin ṣi oju opo Instagraamu fun un lati da a lara ya, awọn aṣọ alarabara to maa n wọ pẹlu ẹrin atata to n fani mọra lori ayelujara to maa n rin, sọ ọ di gbajumọ lẹsẹkẹsẹ ni.
O ti kọwe nipa itan igbesi aye rẹ, bẹẹ lo si ti rinrin oge nihooho ri, eyi to jade loju ewe akọkọ iwe iroyin Rolling Stone, eyi waye nigba ti iya yii wa lẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89).
Ẹnikan to tako keeyan gbó ni, obinrin ni, bẹẹ lo si tun n ja fawọn eeyan to n ni ibalopọ akọsakọ ati abosabo, awọn ọkunrin ti wọn n ṣe bi obinrin ati obinrin to n ṣe bi ọkunrin pẹlu awọn eeyan ti iṣesi wọn yatọ gedegbe (LGBTQ+). O n gbe kara o ṣe rẹgi larugẹ, o si n yi ero awọn eeyan pada lori oju ti wọn fi n wo ara to ti n dagba atawọn to ti darugbo.
Natalia Idrisova, Tajikistan
Onimọ nipa ohun amusagbara lati ara eweko
Awọn obinrin to n gbe lawọn ẹsẹ kuku lorilẹede Tajikistan kii ye koju ipenija ohun amuṣagbara bii ina ẹlẹntiriki tabi igi idana. Natalia Idrisova to jẹ oludasilẹ ajọ kan ti kii se ti ijọba to n ri si ọrọ ayika n sa ipa lati wa ojutu si wahala ipese ohun amuṣagbara yii, ati lati da awọn obinrin lẹkọ nipa awọn ohun alumọni ti Eledumare fi jinkin ẹda pẹlu awọn imọ igbalode nipa ohun amuṣagbara.
Yatọ si idanilẹkọ, ajọ rẹ a tun maa fun awọn obinrin l’awọn ohun elo idana ti kii lo ina manamana pupọ, ile idana ati ohun elo sise irẹsi to n lo itansan oorun gẹgẹbi ohun amuṣagbara, eleyi to n fun awọn obinrin yii laaye sii, ti o si tun nlo ọna ọrọ ayika lati tun ro oko si idi ilana aparo kan ko ga ju ọkan laarin akọ ati abo.
Ni bayii, Idrisova n da awọn ileto lẹkọ lori ọna ti ayipada oju ojọ n gba kan awọn akanda ẹda ati ọna lati rii daju pe olukuluku lo n sọrọ lori ọrọ naa ti awọn alaṣẹ n tẹti si ero wọn.
Awọn iṣẹlẹ laabi kan to n ṣẹlẹ lagbaye n ki wa nilọ pe eniyan ko lee yapa si awọn iṣẹda yooku. A ko lee maa hu iwa tani yoo mu mi si awọn iṣẹda Eleduwa yooku lai ni ri atubọtan rẹ
Natalia Idrisova
Vee Kativhu, Zimbabwe/UK
Oludanilẹkọ lori ẹrọ ayelujara
Vee (Varaidzo) Katibhu ni ọrọ ikẹkọọ rẹ jẹ moriya fun ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan jakejado agbaye. Lakoko to wa nile-ẹkọ naa lo n ṣiṣẹ pẹlu ile ounjẹ McDonald, to si tun pada kẹkọ gboye ni fasiti Oxford ati Havard.
Nigba to wa ni fasiti, o ṣe idasilẹ oju opo kan ni ikanni YouTube lati maa ṣe afihan awọn adojukọ rẹ gẹgẹ nii akẹkọọ to wa lati idile to ku diẹ kaato fun, ati lati ṣalaye ọna ifarada ati igbiyanjui lati ja ajabọ fun awọn miran bii tirẹ.
Lati igba yii wa, Kativhu ti ṣe idasilẹ ‘Empowered by Vee’ leyi to fi n ṣe iranwọfun awọn to kudiẹ kaato fun jakejado agbaye lati ni anfani ile-ẹkọ giga.
O ti kọ iwe kan pẹlu iriri rẹ lati ṣe iranwọ fawọn ọdọ, o si n kẹkọ lọwọ lati gboye ọmọwe ninu idanilẹkọ.
Huda Kattan, Amẹrika
Oludasilẹ Okowo Oge
Wọn bi si orilẹede Amẹrika si idile awọn eeyan kuro Iraq wa gbe ni Amẹrika. Huda Kattan dagba ni Oklahoma, to si fi isẹ alakọwe silẹ lati tẹle sise isowo oge to jẹ eyi to ti wu lọkan tipẹ.
Lẹyin to lọ kọ imọkumọ ni ile ẹkọ oge sise ni Los Angeles, o bẹrẹ si ni akọjọ awọn ilumọka eeyan ati awọn eeyan lati idile ọba kaakiri agbegbe Middle East gẹgẹ bi onibara.
O jẹ onisowo oge ti ọpọ eeyan to le ni adọtaa milọnu ololufẹ to n tẹle lori opo ayelujara Instagram.
Kattan da ileeṣẹ oge ti rẹ, Huda Beauty silẹ lọdun 2013 nipa sise ifilọlẹ ayedẹrun irun to n se oju.loge Lonii, okowo rẹ to ni akojọ ọpọlọpọ bilọnu, to si ti sẹda ohun isaralore to le ni ojoje, ti wọn si n taa ni ile itaja 1,500 kaakiri agbaye.
Sophia Kianni, US
Akẹkọọ ati oniṣẹ-adani
Lẹyin to bawọn ẹbi rẹ sọrọ ni Iran, oniṣowo-adani, Sophia Kianni rii pe imọ diẹ lo wa nipa ayipada oju-ọjọ ni ede wọn. Bayii ni o bẹrẹ si ni ṣe ongbufọ si ede Farsi
Eleyii lo pada di nla ti o si ṣe agbekalẹ eto Climate cardinals, Eto to nii ṣe nipa awọn ọdọ ati bi wọn ti le ṣe ongbufọ si ede kọọkan ati lati jẹ ki o di lilo fawọn fawọn ti ko gbọ ede Gẹẹṣi.
O ti di ẹgbẹrun mẹwaa awọn akẹkọọ bayii ti wọn fi ara wọn silẹ kaakiri ọgọrin orilẹede. Wọn ti ṣe ongbufọ miliọnu kan ọrọ nipa oju ọjọ si ede to le ni ọgọrun.
Afojusun Kianni ni lati ṣe atupalẹ awọn ohun to di koko ninu ede nipa imọ sayẹnsi si gbogbo agbaye.
Awọn ọdọ ajijagbara ti ṣe agbekalẹ eto lori oju ọjọ, wọn ti ko miliọnu eeyan jọ lati ṣe ifẹhonuhan, Wọn ti ṣe atilẹyin fun ẹgbẹẹgbẹrun atako awọn epo to n ṣakoba, bakan naa ni wọn si ti ko ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu dọla jọ lati ṣagbatẹru eto lori oju ọjọ. Ipenija aye yii pọ ju ki a kawọn gbera nitori ọjọ ori tabi iriri wa lọ.
Sophia Kianni
Arati Kumar-Rao, India
Oluyawọran
O n ṣiṣẹ kaakiri orileẹde South Asia. O jẹ oluyaworan to da duro, akọwe ati aṣawari ilẹ Arati Kumar-Rao, o n ṣe akọsilẹ awọn ayipada oju ọjọ.
O n ṣe akọsilẹ finifini nipa bi omi inu ilẹ ṣe n dinku, bibajẹ ibugbe ati lilo ilẹ fun ile iṣẹ atawọn ile to wọ, ti o mu milliọnu eeyan di alairilegbe to si n paa awọn nkan abẹmi run.
Kumar-Rao ti kaakiri orileẹde India fun ọdun mẹwaa, awọn itan rẹ n ṣafihan bi bibajẹ ibugbe ṣe le ṣakoba fun igbe aye ati nnkan abẹmi.
Iwe rẹ, Marginlands: India's Landscapes on the Brink’ṣafihan awọn iriri awọn olugbe agbegbe wọnyii.
Ipinlẹ gbogbo wahala oju ọjọ yii ni omi, ilẹ ati atẹgun ti a padanu. O pọn dandan ki a ṣawari asopo yii.
Arati Kumar-Rao
Marijeta Mojasevic, Montenegro
Ajafẹtọ Awọn Alailera
Lẹyin to boriyọ lọwọ aisan rọparọsẹ lẹẹmeji ọtọọtọ nigba ti o wa ni ile ẹkọ girama, igbesi aye Marijeta Mojasevic yipada pẹlu iyalẹnu.
Lẹyin ti o ni iriri awọn nipa ti ara ati ihuwasi, pupọ ninu eyii ti o ṣi wa pẹlu rẹ titi di oni, Mojasevic n ṣiṣẹ bayii gẹgẹ bii oludamọran fun awọn ọdọ ati ẹni to n ja fun ẹtọ awọn alailera.
O n lo ohun rẹ lati koju awọn iwa ati awọn ihuwasi si awọn eniyan si ẹni to ni ipenija ara.
O ṣe agbekalẹ awọn idanileko ti o pe ni 'Life With Disability', nibi ti o n lo awọn iriri rẹ lati ṣe iranlọwọ fun awọn ti aye n korira wọn.
O jẹ aṣoju fun 'OneNeurology', agbekalẹ eyii ti o ni ifojusun lati jẹ ki ipenija ara di nnkan to nilo amojuto ni gbogbo agbaye.
Sarah Ott, US
Wiwa ọjọ-ori ni ipinlẹ AMẸRIKA ti Florida lẹyin 9/11, olukọ ile-ẹkọ Sarah Ott sọ pe o jẹ ipalara si alaye ti ko tọ.
Bo tilẹ jẹ pe o kẹkọọ ninu imọ sayẹnsi, fun igbo diẹ, o ṣiyemeji pe iyipada oju ọjọ n ṣẹlẹ gan-an.
Gbigba pe oun ṣe aṣiṣe ni igbesẹ akọkọ ninu wiwa otitọ rẹ. Irin-ajo rẹ ti mu ki o di aṣoju iyipada oju-ọjọ pẹlu Ile-iṣẹ Orilẹ-ede fun Ẹkọ Imọ-jinlẹ.
Bayi ti o ti wa ni ipinlẹ Georgia, o nlo iyipada oju-ọjọ lati kọ awọn imọ-jinlẹ si awọn ọmọ ile-ẹkọ rẹ lati ṣe akiyesi awọn ọran ayika ni agbegbe rẹ.
Botilẹjẹpe iyipada oju-ọjọ jẹ ipo “All hands on deck”, a kan le ṣe gbogbo rẹ fun ara wa. Akitiyan dabi ọgba ajara. O jẹ asiko. O jẹ isinmi. Ọwọ awọn akoko ti o ba wa ni.
Sarah Ott
Jetsunma Tenzin Palmo, India
Bhikṣuṇī, Alufaa Buda
Aarin ọdun 1940 ni wọn bi Jetsunma Tenzin Palmo, ko to pe ẹni ogun ọdun lo ti gba ẹsin Buda.
Nigba to pe ẹni ogun ọdun, o rinrinajo lọ si orilẹ-ede India, nibi to ti di ọkan lara awọn oyinbo alawọ funfun akọkọ ti wọn yoo fun ni oye alufaa Buda, iyẹn ‘Tibetan Buddhist.’
Ninu igbiyanju rẹ lati ṣe igbeleke awọn obinrin to n ṣe ẹsin Buda, Tenzin Palmo ṣe idasilẹ Dongyu Gatsal Ling Nunnery, to wa lagbegbe Himachal Pradesh, ni India, nibi ti nnkan bii ọgọfa alufaa Buda n gbe.
O gbajumọ fun gbigbe lagbegbe to jina rere si aarin igboro ninu iho apata kan lagbegbe Himalaya, nibi to jẹ ọkan lara awọn agọ to ṣe pataki fun awọn to mu ẹsin naa ni pataki. Lọdun 2018, wọn fi jẹ oye Jetsunma, to n tumọ si ‘ọga patapata.’
Lala Pasquinelli, Argentina
Ayaworan
Women Who Were Not On a (Magazine) Cover jẹ oun ti Lala Pasquinelli dasilẹ loọdun 2015 lati tako awọn ilana bi o ṣe yẹ ki obirin ri lawujọ ati bi wọn ṣe n soju obirin lawujọ laye ode oni.
Iṣẹ agbese yii lowa lẹyin awọn ipolongo to n ṣe atunyẹwo bi eeyan ṣe n ri ara rẹ si paapaajulọ nipa ọrọ didagba ati ounjẹ jijẹ. Ipe wọn kan laipẹ yii ni #HermanaSoltaLaPanza (arabirin ma se ikun rẹ ki) ti o saami si itan aye awọn eeyan oniruuru apẹrẹ ati iwọn.
Pasquinelli jẹ agbẹjẹro, akewi, ẹni to feran ibasepọ abo si abo ati ajafẹto obirin to n ṣiṣẹ lati mu atupalẹ ba irinisi awọn obirin lawujọ nitoripe o ni wọn wa "classist, sexist and racist" ti wọn si n mu ki aidogba gberu si laarin abo ati akọ.
Jess Pepper, UK
Oludasilẹ ibi ọrọ sisọ nipa oju ọjọ
Ibi isọrọ oju-ọjọ jẹ awujọ tawọn eeyan ti maa n pade pọ lati mu nkan, takurọsọ ati gbe igbesẹ lori iyipada oju ọjọ. Jess Pepper lo ṣe ifilọlẹ akọkọ iruẹ lọdun 2015 ni abule Birnam orilẹede Scotland to wa ni Perthshire.
Ni bayii, o ti n gbaruku ti awọn awujọ mii lati bẹrẹ tiwọn naa, o n so wọn papọ kari aye.
Awọn to wa labẹ iadnilẹkọọ bẹẹ ni ibi tawọn ti le jiroro nipa iyipada oju ọjọ ni.
Pepper di oniruuru ipo olori mu nipa ọrọ oju ọjọ, o si jẹ ọmọ ẹgbẹ ọmọba ilẹ Scotland to ri si ọrọ awujọ(Royal Scottish Geographical Society) ati ọmọ ẹgbẹ ọmọba to n ri si iṣẹ ọna(Royal Society of Arts).
Igbesẹ to dara n waye lori iyipada oju ọjọ kaakiri awujọ, awọn obinrin atawọn ọmọde gan an maa n ṣagbatẹru rẹ. Bi mo ṣe n ri bawọn eeyan ṣe n tẹwọgba iyipada atawọn anfaani to n jẹyọ debi ọrọ oṣelu maa n fun mi ierti.
Jess Pepper
Matcha Phorn-in, Thailand
Ajafẹtọ Ibalopọ ẹda ara kan naa LGBTQ ni Thailand
Ala orilẹede Thailand ati Myanmar ni ibugbe rẹ.Agbegbe naa si kun fun oniruru ipenija oju ọjọ pẹlu dukuu ọjọ gbọgbọrọ.Ẹtọ awọn ẹya kerejekereje ni Match Phorn-in gbajumọ julọ.
Oun ni Oludasilẹ ajọ Sangsan Anakot Yawachon Development Project, to n moju to idanilẹkọ ati riro awọn obinrin ati ọdọbinrin ti ogun sọ di alarinkiri, pẹlu awọn ọdọ to darapọ mọ awujọ awọn abẹda ara kan naa lo pọ, LGBTQ+
Matcha Phorn-in tun n kopa ribiribi lati dawọ hihu iwa ipa si awọn obinrin duro lagbegbe naa. Bakan naa lo tun n ja fun ẹtọ ọmọ onilẹ ati oju ọjọ fun awon ogunlende ati awọn ti ko lẹtọ lati dibo.
Lai si ipa awọn olugbe awọn agbegbe tọrọ kan, ko si bi a ṣe le ri ojutu si wahala ọrọ oju ọjọ.
Matcha Phorn-in
Carolina Díaz Pimentel, Peru
Akọroyin
Nigba ti awọn dokita sọ fun pe o ni autism ni igba to wa logun ọdun,niṣe ni Carolina Díaz Pimentel ṣeto akara eebo ta mọ si cake lati fi yọ ayọ pe ohun yatọ si awọn eeyan mii.
Bayi to ti pe ọgbọn ọdun le iṣẹ akọroyin lo n ṣe to si yan iroyin nipa awọn akanda laayo.
Díaz a tun maa gbiyanju lati mu opin ba idẹyẹsi ti awọn to ni ipenija ara n koju lawujọ. O jẹ oludasilẹ aimọye ajọ ẹlẹyinju aanu bi Mas Que Bipolar (More than bipolar), Peruvian Neurodivergent Coalition ati Proyecto Atípico (Project Atypical).
Wọn ti ṣe idanimọ ẹyẹ fun labẹ Pulitzer Center to si tun jẹ onimọ labẹ ajọ Rosalynn Carter
Shairbu Sagynbaeva, Kyrgyzstan
Okan lara awọn oludasilẹ ileeṣẹ aranṣọ For Life
Lẹyin to fi ọdun mẹrin gbako gba itọju arun jẹjẹrẹ to wa ni ipele kẹrin ti ko si ri owo lati san owo oogun itọju rẹ, ara rẹ ti n balẹ diẹdiẹ.
Oun atawọn alaarun jẹjẹrẹ mẹrin mii ti ara wọn ti n balẹ da ileeṣẹ aranṣọ ‘For Life’ silẹ nibi ti wọn ti n ran baagi ti wọn si n ta baagi naa atawọn nnkan mii, eyi ti wọn n fi owo rẹ ṣọwọ si awọn to ni arun jẹjẹrẹ fun itọju.
Wayi o, wọn ti ko owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn dọla jọ, eyii ti wọn fi ṣeranwọ fun obinrin mẹrinlelọgbọn ti wọn ko ri owo itọju wọn san.
Sagynbaeva ri pe ọpọ awọn to n gba itọju arun naa lo n gbe nibi to jina rere sile iwosan eyii to mu ko kọ ile kan si itosi ile iwosan ti wọn le maa gbe.
Daria Serenko, Russia
Akewi
Daria Serenko je onkọwe ati olupolongo iṣelu rere jẹ ọkan lara awọn alakoso Feminist Anti-War to tako ogun ti Russia gbe ti Ukraine.
Lati ọdun mẹsan an sẹyin ni o ti n ko nipa hihu iwa ipa si awọn obirin ni ilẹ Russia, o si ti kọ iwe meji nipa ẹto obirin ati aidara ogun jija.
Serenko jẹ oludasile Quiet Pickett, ileesẹ ti o ti ma n lo lati fi gbe iwe akiyesi jade ni gbangba lati fi se itaniji fun awọn eeyan lori koko ọrọ kan tabi omiran.
ọsẹ meji saaju asiko ti Russia yoo bẹrẹ ikolu rẹ si ilẹ Ukraine ni awọn agbofinro gbe Serenko fun ẹsun wipe o n fi ọrọ awọn alakatakiti lede. Laipẹ ni o ko kuro lọ si ilu Georgia. Ni bayii ijọba ilu Russia ti saami sorukọ rẹ gẹgẹ bi 'oluranlọwọ awọn ajeji'.
Kera Sherwood-O'Regan, New Zealand
Ajafunẹ̀tọ́ àwọn Akanda ẹ̀da ati ohun ibilẹ̀
Kera Sherwood-O’Regan jẹ ọmọ bibi ẹya Kai Tahu ni Te Waipounamu, ni South Island ni orilẹ-ede New Zealand.
O jẹ akóṣẹmọṣẹ nipa ayipada oju ọjọ ko tó wa lara awọn oludasilẹ ‘Activate’ eyi to jẹ ajọ to n risi ọrọ idajọ ayipada oju ọjọ ati ayipada awujọ.
Kera maa n ṣamulo ilana ‘Maori’lori ọrọ ilẹ̀ ati awọn to ti re ibi agba n re ni eyi ti awọn kan ko ka kún ninu ijiroro naa.
O ni ajọṣepọ to dan mọran pẹlu awọn Minista, awọn aṣoju ijọba ati awọn ẹgbẹ tp n risi ipa ti ayipada oju ọjó n ko ni awujọ rẹ, Bakan naa lo tun n ja fun ẹtọ awọn ara ilu ati awọn akanda ẹda to ni aabọ ara ninu ijiroro ayipada oju ọjó naa.
A n kọ awọn ilana ti ko tọna tó, a n gba aaye sii ki a le ṣoju awọn agbegbe bi o ti yẹ; ni eyi to n ṣiṣe bayii. Mo ro pe ópó gba pe mimọ sii nipa agbara abalaye ni ọna abayọ si iṣoro to n koju ayipada oju ọjọ.
Kera Sherwood-O'Regan
Sagarika Sriram, United Arab Emirates
Olukọni ati oludamọran nipa oju ọjọ
Ọdọ ni Sagarika Sriram, o si n ja lati jẹ kawọn ile-ẹkọ mu ẹkọ nipa oju ọjọ lokukudun.
Lilo imọ rẹ nipa 'coding', o da ikanni ayelujara; 'Kids4abetterworld' silẹ, eyii to n kọ awọn ọmọde kaakiri agbaye ati lati ṣatilẹyin fun awọn eto igbeaye lagbegbe wọn.
O n ṣe eleyi pẹlu ẹkọ lori ayelujara ati ninu kilaasi, to n kọ awọn ọmọde bi wọn ṣe le ni ipa rere lori oju ọjọ.
Yatọ si pe o n kẹkọọ lati gboye 'A-levels' nilu Dubai, Sriram jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn ewe to n damọran fun ikọ ajọ UN lori ẹtọ awọn ọmọde, nibi to ti n gbe ẹtọ nipa agbegbe ga.
Kii n ṣe asiko fun ariwo ṣugbọn fun iṣẹ, gbogbo ewe lo yẹ ko ni imọ lati le gbe igbeaye irọrun ninu nile aye ati lati mu ayipada to yẹ ba agbaye.
Sagarika Sriram
Clara Elizabeth Fragoso Ugarte, Mexico
Awakọ̀ ńlá tírélà
Ọdún mẹ́tàdínlógún ni awakọ̀ ńlá Clara Elizabeth Fragoso ti fi ara rẹ̀ jìn sí ìdí iṣẹ́ tó jẹ́ pé àwọn ọkùnrin ló máa ń ṣe é. Fragoso Ugarte máa ń wa ọkọ̀ rẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Mexico pàápàá lórí àwọn ọ̀nà tó léwu.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Durango ni, Fragoso Ugarte lọ sí ilé ọkọ nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tó sì bí ọmọ mẹ́rin. Bákan náà ló ti ní ọmọọmọ méje.
Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń wa ọkọ̀ ńlá, ojú ọ̀nà ló ti máa lo ìgbésí ayé rẹ̀ nípa jíjà ọjà káàkiri Mexico àti US.
Ó tún máa ń kọ àwọn awakọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ ní ọkọ̀ wà, tó sì tún máa ń ṣe kóríyá fún àwọn obìnrin láti darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ náà kí obìnrin náà le pọ̀ nídìí rẹ̀.
Louise Mabulo, Phillipines
Agbẹ ati olokoowo aladani
Lọdun 2016, Iji lile ati ẹkun omi Nock-Ten lo sọsẹ nla ni agbegbe Camarines Sur lorilẹede Phillipines, to si gba ilẹ oko to to ida ọgọrin ninu ọgọrun.
Louise Mabulo tabuku ajalu yii pẹlu idasilẹ isẹ akanse Cacao ti a tun m si kòkó lẹyin isẹlẹ ajalu naa. Afojusun ẹgbẹ naa ni lati mu ki ilana ipese ounjẹ labẹle pọ yanturulati ipasẹ ọgbin oko to fẹsẹ mulẹ.
Mabulo ro awọn agbẹ lagbara, o ba awọn ilana to n se akoba fun ipese ounjẹ jẹ, to si tun lewaju ninu agbekalẹ ọrọ aje to muyanyan lati ipasẹ isẹ ọgbin nigberiko, to si da akoso ọrọ aje pada sọwọ awọn eeyan to n lo ilẹ lati da oko.
O maa n gbe imọran kalẹ lori awọn ofin to rọ mọ oju ọj lagbaye, nibi to ti maa n tẹnpẹlẹ mọ itan nipa agbegbe igberiko ati imọ wọn. Ajọ to wa fun ọrọ ayika labẹ ajọ isọkan agbaye kan mọriri rẹ bii ọdọ to n lewaju ninu amulo ilẹ.
Mo ni ireti pẹlu bi mo se sawari rẹ pe awọn eeyan bii temi to n lọ soke soke ni agbaye lo n gbe aye ro, ti a si n fọnrere ọjọ ọla to kun fun ilẹ ọgbin, eyi to so ọpọ agbegbe papọ, nibi ti ounjẹ yoo ti sun wa bọ lọpọ yanturu ti yoo si tun wa ni arọwọto wa, nibi ti ọrọ aje wa yoo ti yi wa po, eyi ti ilana ibaradọgba yoo maa dari rẹ.
Louise Mabulo
Oksana Zabuzhko, Ukraine
Òǹkọ̀wé
Oksana Zabuzhko ti kọ ìwé tó lé ní ogún tó fi mọ́ ìtàn gidi, ewì àti ìtàn àròsọ, tí wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára òǹkọ̀wé àti onímọ̀ ní Ukraine.
Káàkiri àgbáyé, wọ́n mọ̀ ọ́ fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ Field Work in Ukrainian Sex, àti The Museum of Abandoned Secrets.
Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Kyiv's Shevchenko University ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Philosophy tó sì tún ti gboyè ọ̀mọ̀wé ninú Philosophy of Arts.
Wọ́n ti tú àwọn ìwé rẹ̀ sí èdè ogún, tí wọ́n sì tún ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹyẹ bíi Angelus Central European Literacy Prize, Ukraine's Shevchenko National Prize àti French National Order of the Legion of Honour.
Idanilaraya ati Ere Idaraya
Aitana Bonmati, Spain
Agbaboolu
Wọn bi Aitana Bonmati to n gba bọọlu lagbedemeji papa nilu Catalonia ti o si ti gbami ẹyẹ bọọlu ti liigi Spain ati Champions League pẹlu ikọ agbabọọlu rẹ Barcelona.
Amọ laarin idije bọọlu agbaye (World Cup) to ti di ilumọka fun ipa to ko ninu aseyori ilẹ Spain ninu idije naa lẹyin to gba bọọlu meta sawọn ti wọn si yan an gẹgẹ bi ẹni to dara julọ lori papa isere ninu idije naa. ọmo ọdun meedọgbọn ni, o si ti gbami ẹyẹ to gajulọ ninu bọọlu gbigba (Ballon d'Or) ti o si tun ti dade ẹni to mọ bọọlu gba ju fun ọdun 2023 lọdọ Uefa.
Ko bẹru lati pe fun ki abo ati akọ jijọ jẹ ọgbọọgba lawujọ ati lori papa isere ati ni ibomiran.
Nigbati ti isẹlẹ laarin olori ajọ elere bọọlu tilẹ Spain Luis Rubiales ati Jenni Hermoso sẹlẹ, ti o fi ẹnu ko ni ẹnu laifayegbaa, ti eleyii si bo aseyori ilu naa ninu idije World Cup mọlẹ, Bonmati satilẹyin fun Jenni ati awọn obirin to n koju iru isẹlẹ bayii nigba to n tẹwọgba ami ẹyẹ rẹ lọdọ Uefa.
Antinisca Cenci, Italy
Ere idaraya lori ẹshin
Nigba ti Antinisca Cenci bẹrẹ ere idaraya lori ẹshin nigba to wa ẹni ọgbọn ọdun, ko lero pe laarin ọdun mẹwaa pe oun yoo ma irin irinajo kaakiri pẹlu ikọ lati ma gbaradi lati se ere idaraya lori ẹshin.
Lati La Fenice, ni apa ariwa Italy, ko ni igbeaye to rọrun. Wọn sọ fun iya rẹ pe Cenci ko le ye otutu lẹyin to n koju idamu lasiko ibi rẹ.
Cenci bẹrẹ ere idaraya lori ẹshin nipasẹ eto kan ni ẹgbẹ ANFFAS gbe kalẹ (Italy's National Association for Families and People with Disabilities) ati ikọ ere idaraya ẹshin La Fenice.
Bayii, o n se igbaradi pẹlu ẹni to gba ami ẹyẹ agbaye, Anna Cavallaro ati akọnimọse Nelson Vidoni.
Andreza Delgado, Brazil
Olutọju aworan ati alakoso nkan asa
Nitori ifẹ rẹ lati mu iriri apejọpọ fun iwe alaworan wa fun awọn alaini ni ita Sao Paulo, Andrea Delgado sowọpọ pẹlu awọn kan lati da PerifaCon silẹ.
Apejọpọ naa ti o jẹ ọfẹ fi oju si awọn onkọwe, ayaworan ati bẹẹbẹẹlọ ti wọn ki n ri iru aaye naa.
Pẹlu iwe aworan, ere igbalode lori fọnran, agbo orin ni ita gbangba ati asa awọn akowe miran, PerifaCon ẹlẹẹkẹta waye loọdun 2023 ti eeyan ẹgbẹrun lọna mẹẹdogun si kopa ninu rẹ.
Nipasẹ lilo ikọnni rẹ lori ayelujara Youtube ati podcast, Delgado n tẹsiwaju pẹlu ipe re fun ijọba Brazil lati gba ki awọn ayaworan alawọdudu naa le ma gbe aṣa wọn larugẹ ni ilu naa.
Desak Made Rita Kusuma Dewi, Indonesia
Ayaragunke
Nigba to wa nile-ẹkọ alakọbẹẹrẹ ni Bali, Desak Made Rita Kusuma Dewi ni wọn pe lati waa gun ogiri, to si pada nifẹ si ka maa fi ere gunke.
Kia lo rọwọ mu nibi idije awọn ọdọ, amọ “ọbabinrin awọ to n gun apata ni Indonesia” lo ti fakọyọ lọpọ igba lọdun yii debi pe o gba ami-ẹyẹ wura nibi idije agbaye awọn obinrin lọdun 2023 pẹlu iṣẹju aaya mẹfa ati abọ.
Aṣeyọri yii lo fun-un ni anfani lati le kopa ni idije olympics to maa waye ni Paris lọdun 2024, nibi ti iyaragunke yoo ti daduro bii idije ti ara rẹ fun igba akọkọ.
O ṣeeṣe ki ayaragunke yii o kọ orukọ ara rẹ sinu iwe itan Indonesia nitori pe wọn ko gba ami-ẹyẹ kankan ri nidii iyaragunke.
America Ferrera, US
Oṣere
Amẹrika Ferrera jẹ ẹni ti ko ṣoroo damọ lagbo idanilaraya, oṣere to ti gba ami-ẹyẹ ni, adari ati alakooso ere ti awọn eeyan mọ fun ọpọlọpọ ere sinima to ti kopa ninu ẹ lo jẹ bi fiimu to gba igboro kan ti wọn pe ni Barbie, pẹlu fiimu mi-in ti wọn pe ni Real Women Have Curves ati Ugly Betty.
Oun ni oṣere to kere julọ to gba ami-ẹyẹ Emmy labala awọn agba oṣerebinrin to kopa ninu fiimu Ugly Betty ati Latina akọkọ (First Latina). Ajafẹtọ ọmọniyan fọdun pipẹ ni, agbolohun bi ọjẹ lori ẹtọ obinrin ni Ferrera, o si maa n kede pe obinrin gbọdọ ni aṣoju to pọ lori amohunmaworan.
Ọmọ arin-rin-ajo lati Honduras ni, o si ma n ṣe ipolongo fun ilọsiwaju igbesi aye awọn eeyan Latina l’Amẹrika, o n ṣe eleyii nipasẹ eto rẹ to gbe kalẹ , Poderistas, ti ki i ṣe lati ko ọrọ̀ kankan jọ.
Anne Grail, France
Alawada
Ẹgbẹ alawada Greenwashing jẹ ẹgbẹ to parapọ lati dojukọ awọn ọrọ to kan ayika ati ẹtọ awọn obinrin, isẹ, aidape ara ati ẹtọ awọn isẹda kan naa to n fẹ ara wọn.
Adẹrinposonu Anne Grail lo da ẹgbẹ naa silẹ, ẹni to gbagbọ pe lati ipasẹ awọn awada, o seese ki eeyan gbin irugbin ayipada rere si ọkan awọn eeyan , ko si tun mu ayipada ba ihuwasi wọn.
Ni awujọ ti eto idanilaraya ti jẹ itẹwọgba, ti ero ati ọrọ kekere si maa n gbakoso fun igba pipẹ, Grail gbagbọ pe awada to da lori asọdun lee jẹ ọna to pegede julọ lati se alabapin ero to rọ mọ ayipada oju ọjọ
Aseyori ẹgbẹ alawada Greenwashing dun mọ ni lọkan nitori o fihan pe lonii, ọpọ eeyan ni ọrọ ayipada to n ba oju ọjọ ka lara, ti wọn si fẹ korajọ pọ lati rẹrin, ki wn si fi ibudo idanilaraya naa silẹ pẹlu erongba ọkan lati maa tẹsiwaju ninu ogun ti wọn n gbe ti ayipada oju ọjọ.
Anne Grail
Georgia Harrison, UK
Eni to n sise ni ileese amohun-maworan
Leyin ti Geogia Harrison di eni ti won ṣe asemase pelu re nipase aworan, o ṣe pinu lati fi itan re satileyin fun gigbogun ti iwa ipa lori awọn obirin ki o si mu ayipada ba bi ile Geesi se mọ ifohunṣọkan si.
Eni to n ṣiṣẹ ni ileese amohun-maworan ti o jẹ ilumọka latari awọn eto idanilaraya rẹ bi Love Island ati The Only Way is Essex, se asiwaju ipolongo bi ayipada se ma de ba ofin ile Geesi to pese aabo fun awọn to n lo ayelujara lati lo aworan lona aito ti won pe ni 'revenge porn'.
Harrison n pe fun ofin to nipọn lati koju iwa lilo aworan ati fọnran ni ilokulo lori awọn oju ewe to wa lori ayelujara lai gba aṣẹ.
Harmanpreet Kaur, India
Elere idaraya kirikẹẹti
Ọdun 2023 ni Harmanpreet Kaur di ọmọ orilẹ-ede India akọkọ ti wọn yoo fun ni ami ẹyẹ ‘Wisden's five Cricketers of the Year.’
Harmanpreet Kaur ni balogun ikọ kirikẹẹti obirnin orilẹ-ede India, o si ti sọ ọppọlọpọ ayo sinu awọn nile loko. Lọdun to kọja, oun pẹlu ikọ rẹ ṣe aṣeyọri to ṣe e mu yangan ninu idije Commonwealth.
Labẹle ni India, o wa lara ikọ to gba ami ẹyẹ idije ‘Women's Premier League’ akọkọ nilẹ naa.
Lara awọn aṣeyọri rẹ ni bo ṣe sọ bọolu 171 sawọn fun India ninu idije Women's World Cup lasiko ti wọn koju orilẹ-ede Australia, eyii to gbe wọn de aṣekagba idije ọhun.
Dayeon Lee, South Korea
Onipolongo fun Kpop4Planet
Nipasẹ Kpop4Planet, Dayeon Lee n ko awọn ololufẹ K-pop ni l’agbaye lati koju idaamu oju-ọjọ.
Lati ifilọlẹ rẹ ni ọdun 2021, ẹgbẹ ipolongo naa ti beere lọwọ awọn eniyan ti o ni ipa ere idaraya ni South Korea lati ṣe iṣe oju-ọjọ, ati iyipada si oun amuṣagbara.
Ẹgbẹ naa ti ṣe afihan awọn ewu ti awo orin n da silẹ l’ayika, eyiti o fa awọn eeyan to l’aami ni K-pop lati yipada si awọn awo-orin ayelujara.
Dayeon Lee ti lọ kọja kikọ orin, lati koju awọn adehun oju-ọjọ ti awọn ile ise aṣọ igbalode, eyiti to n ṣe afihan awọn gbajugbaja K-pop bi oju gbangba wọn.
Nigba ti a ba n pe fun idajọ ododo lawujọ, a ko gbọdọ dawọduro titi a fi ma ri ayipada. A ti ṣeleyii lọpọ igba, a o si maa ṣe e lọ, a maa ma gbogun ti kiko ijamba ba oju ọjọ.
Dayeon Lee
Justina Miles, US
Elere idaraya to ni ipenija eti
Justina Miles fitan balẹ nibi ayẹyẹ ere idaraya onigbagede nla (Super Bowl LVII) to waye loṣu keji, iyẹn ọkan ninu awọn ere idaraya tawọn eeyan maa n woju lagbaaye.
Okiki elere idaraya to ni ipenija eti yii gba ori ayelujara kan nigba to fi ilana fifi ọwọ sọrọ, kọ ọrin gbajugbaja olorin, Rihanna, to si ṣe kinni ọhun to mu ori awọn eeyan wu gidi.
Ohun to ṣe yii lo sọ ọ dobinrin akọkọ to ni ipenija eti to si fi ilana ti wọn n pe ni American Sign Language (ASL) dára nibi ayẹyẹ nla Super Bowl. Eyi akọkọ to ṣe ti o fi ọwọ kọ orin ‘gbe ohun soke ko o kọrin’, - eyi ti o je orin iyin awon alawọdudu - naa tun gba ipo kin-in-ni nibi ayẹyẹ ọhun.
Afojusun Miles ni lati ṣe ojulowo afihan awọn eeyan to ni ipenija eti si gbogbo agbaye, o si nireti lati da ibudo tiẹ silẹ ti yoo ti le kọ ọpọ nọọsi ti wọn ni ipenija eti.
Dia Mirza, India
Oṣere
Kii ṣe pe oṣere Dia Mirza gba awọn ami-ẹyẹ fun awọn ipa rẹ ninu sinima India nikan, ṣugbọn o tun kopa ninu ọpọlọpọ awọn iṣẹ akanṣe ayika ati Itẹsiwaju ọmọniyan.
Gẹgẹ bii aṣoju Eto Ayika fun ajọ iṣokan agbaye, United Nations, Mirza ri si itankalẹ awọn ipenija to niiṣe pẹlu oju ọjọ, afẹfẹ to mọ, ati aabo fun awọn ẹranko.
Oun ni oludasile awọn fọnran itan, 'One India Stories', ileeṣe to n se akojọpọ itan to ni afojusun lati la ipa rere, gẹgẹ bi o ṣe sọ, "ti yoo mu ki o dẹsẹ duro ki o si ronu".
O tun jẹ aṣoju fun ajọ 'Save the Children, International Fund for Animal Welfare', ati aṣoju igbimọ ajọ 'Sanctuary Nature Foundation'.
Zandile Ndhlovu, South Africa
Olukọ wiwọ okun lai lo afẹfẹ atọwọda lati mi
Gẹgẹ bii obinrin akọkọ ti yoo jẹ olukọ wiwọ okun lai lo afẹfẹ atọwọda lati mi, Zandile Ndhlovu ni oun fẹẹ ki awọn to n wọnu okun o pọ sii.
O da ẹgbẹ ‘The Black Mermaid Foundation’ silẹ leyi to n fi oju awọn ọdọ atawón ileto mọ oku pẹlu afojusun pe wọn yoo le loo9 fun igbafẹ ati ere idaraya.
Ndhlovu jẹ ẹni to nifẹ okun, onkọtan, ati oṣere. O n lo gbogbo ẹbun yii lati ṣe agbekalẹ awọn ọdọ ti yoo maa moju to imọtoto okun, ẹkun omi ati kikopa ninu idaabobo agbegbe wọn.
Rironu nipa ohun awọn ọdọ ti wọn pe fun ayipada lawujọ ma n fun mi ni ireti lori rogbodiyan oju-ọjọ
Zandile Ndhlovu
Alice Oseman, UK
Òǹkọ̀tàn nípa ìyàwòrán
Òǹkọ̀wé tó dáńtọ́, olùyàwòrán, Alice Oseman ni ṣe ìwé àwòrán fún àwọn ọ̀dọ́ tó tà lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ti ṣe àyípadà ìtàn LGBTQ+ coming-of-age sí ìtàn tó gba àmì ẹ̀yẹ Emmy fún Netflix.
Oseman kọ eré náà ní ẹsẹẹsẹ àti pé ó kópa nínú ṣíṣe rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin tó fi mọ́ àwọn òṣèré tí wọ́n lò àti orin tí wọ́n lò nínú eré náà.
Bákan náà ló tún ti kọ àwọn ìwé mìíràn fún àwọn ọ̀dọ́ bíi Radio Silence, Loveless àti Solitaire, tó gbé jáde nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.
Àwọn ìwé rẹ̀ tí gba àmì ẹ̀yẹ, tí wọ́n sì tún forúkọ sílẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ tó fi mọ́ YA Book Prize, the Inky Awards, Carnegie Medal àti Goodreads Choice Awards.
Paramida, Germany
DJ' ati olupilẹṣẹ orin
Saaju ki ifehonuhan to bẹrẹ ni Iran ni ọdun to kọja, DJ Paramida ti n boriyọ ninu gbedeke ati odiwọn aṣa fun awọn obinrin Iran.
Ni bayii ti o di olugbe ilu Berlin, Paramida ṣe awari ifẹ rẹ fun orin ati aṣa ijo jijo lasiko to ń gbe laarin Frankfurt ati Tehran ni igba ewe rẹ.
Nipasẹ akọsilẹ imisi orin ati ijo alailẹgbẹ to ni, ileeṣẹ to n gbe awo orin rẹ jade, 'Love On The Rocks' n ṣe agbatẹru orin ati aṣa ijo igbalode lonii.
Gẹgẹ bi olugbe ti 'Berghain's Panorama Bar' ni Berlin, o ti di DJ ti wọn n fẹ ni gbogbo agbaye ati olupese orin ti o ṣe aṣeyọri. O n lo aye yii lati koju awọn ipenija ti awọn obinrin ni lẹka isẹ orin, idaraya ati faaji ọwọ alẹ ti awọn ọkunrin pọ si julọ.
Camila Pirelli, Paraguay
Ẹni to ti gba ami ẹyé ati goolu ere idaraya ninu Olympic
Camila Pirelli kopa ninu idije 100 mita ninu ere sisa ninu Olympic to waye ni orilẹ-ede Tokyo.
Gurani Panther ni epejẹ́ orukọ ti ọpọ maa n pe akọṣẹmọṣẹ to n sare ni, Camila Pirelli. O ti gba ami ẹyẹ to pọ, o n kọ awọn eeyan sii niap ere idaraya bẹẹ lo si n kọ wọn ni ede oyinbo ni ilu rẹ.
O dagba laarin awọn to nimọ nipa ayika wọn ninu ilu kekere Paraguay nibi to ti ri ipa yaipada oju ọjọ ninu iriri rẹ.
Bayii, Camila ti di akọṣẹmọṣe elere idaraya to n lo awọn ohun to wa ni ikawọ ré lati fi kọ awọn eeyan sii nipa mimojuto ayika wón ati gbigbogun ti iṣoro ayipada oju ọjọ.
Bi mo ṣe dagba ninu ilu ti a ti n ri ẹranko igbẹ lojoojumọ jẹ ki n mọ iṣoro ti awọn eranko igbo yii n koju nipasẹ ayipada oju ọjọ ni eyi to n yọ ọkan mi lẹnu to si jẹ ki n pinnu lai ṣe iranlọwọ to wa ni ikawọ mi.
Camila Pirelli
Aziza Sbaity, Lebanon
Asare ori ọdan
Aziza Sbaity gba iyi gẹgẹ bii obinrin ọmọ orilẹ-ede Lebanon to le sare julọ ninu itan ninu ere ije 100m, o si gba ami ẹyẹ gẹgẹ bii alawọ dudu akọkọ lati orilẹ-ede rẹ to gba ami ẹyẹ wura ninu idije ‘West Asian and Arab championships’ lọdun yii.
Ọmọ orilẹ-ede Liberia ni iya rẹ nigba ti baba rẹ jẹ ọmọ orilẹ-ede Lebanon. O gbera lọ si Lebanon nigba to wa lọmọ ọdun mọkanla nibi to ti kọju ija si iwa ẹlẹyamẹya.
Idije ere sisa lo fun Aziza lanfani lati kede ara rẹ gẹgẹ bii ajafẹtọ ọmọniyan.
O maa n lo ipo rẹ lati sọrọ lodi si ẹlẹyamẹya lorilẹ-ede rẹ, o si n ṣe eyii pẹlu ajọṣepọ awọn ile ẹkọ atawọn fasiti ni Lebanon lati yi irori awọn ọdọ orilẹ-ede naa pada.
Khine Hnin Wai, Myanmar
ọṣere
Nkan bi ọdun marundinlọgbọn lo bẹrẹ iṣẹ oṣere ni Myanmar to si di ilumọọka tori ipa to ko ninu fiimu San Ye. O tibẹ wa di gbajumọ oṣere ni ẹka sinima Burna.
Amọ iwa ẹlẹyinju aanu l'awọn eeyan mọ fun bayii.bNi 2014 o da ajọ ẹlẹyinju aanu Khine Hnin Wai Foundation silẹ eyi to n satilẹyin fawọn to ba n ṣe itọju ọmọ orukan ati awọn ọmọ ti wọn pati lawujọ.
Nipa iṣẹ to n ṣe ọmọ ọgọrun ni ajọ yi n tọju tí awọn obi wọn ko ni ikapa lati tọju wọn.
O tun jẹ aṣoju fun igbiyanju lati kọdi fifi ọmọde ṣe owo
Bianca Williams, UK
Elere idaraya
Bianca Williams jẹ ẹni to ti gbami ẹyẹ goolu fun sisa ere 4x100m, o si jẹ balogun fun ilẹ Geesi ati Ireland ninu European Team Championships fun ọdun 2023
Ni osu keje, o gba ipo keji ninu ere sisa 200m ni UK Athletics Championships lati wo aarin awọn to soju ilẹ Geesi ni World Athletics Championships nilu Budapest
Awon olopaa ni London da oun ati ẹnikeji rẹ Ricardo Dos Santos to jẹ elere idaraya bi tirẹ duro ti wọn si yẹ ara wọn wo.
Williams ati Dos Santos kọ iwe ehọnu ranse nipa iwa awọn ọlọpaa yii ti wọn si fẹsun sise aida nitori ọrọ ẹlẹyamẹya kan wọn.
Oṣelu ati Itaniji
Maryam Al-Khawaja, Bahrain/Denmark
Olupolongo eto iṣelu rere to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan.
Maryam Al-Khawaja jẹ aṣaaju ninu awọn to n beere fun eto iṣelu rere ni Danish-Bahraini ni Bahrain ni ẹkun Gulf.
Iṣe to ti ṣe n ṣafihan jija fun ẹtọ ọmọniyan ni awujọ paapaa lori pe ki wọn fi Baba rẹ Abdulhadi Al-Khawaja silẹ nibi ipolongo #FreeAlKhawaja.Abdulhadi yii jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan to wa ni ẹwọn gbere lẹyin to kopa nibi iwọde eto iṣejoba awa-ara-wa lọdun 2011.
Al-Khawaja ti dari igbimọ lorisiiriṣii bii ti ‘Civicus’ ati awọn ajafẹtọ ọmọniyan kaakiri agbaye. O tun ti ṣiṣẹ pẹlu awọn ọdọbinrin ti wọn wa ni ajọ FRIDA ti wọn n ja fun ẹtọ awon obinrin ati awọn oniṣegun oyinbo ti wọn n ja fun ẹtọ ọmọniyan ni agbaye.
Shamsa Araweelo, Somalia/UK
Olupolongo gbigbogun ti didabẹ f'ọmọbinrin
Latari ipinnu rẹ lati rii pe opin de ba didabẹ f’awọn ọmọbinrin, Shamsa Araweelo lo n ṣe idanilẹ ati ilanilọyẹ nipa rẹ pẹlu a\won fanran to lagbara lori ayelujara.
Araweelo, ẹni ti wọn bi ni Somalia amọ to n gbe ni UK lọwọ yii, ni wọn dabẹ fun lọmọ ọdun mẹfa leyi to tumọ si pe wọn diẹ abi gbogbo nkan ọmọbinrin rẹ to yẹ ko jade sita latari awọn idi ti ko ni nkankan ṣe pẹlu ilera rẹ.
Pẹlu awọn to le ni aadọrin miliọnu to ti wo awọn fanran rẹ loju opo Tiktok, Araweelo lo wi pe oun ko fẹẹ ki ẹnikẹni wa ti ko tii gbọ nipa fifopin si didabẹ f’ọmọbinrin.
Awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi ti wọn ha s’oke okun atawọn ti mọlẹbi wọn n ṣe bi ko ṣe tọ ni Araweelo n ṣe iranwọ fun lọwọ yii. O si tun fun ajọ ọlọpaa ilu London lamọran lori didabẹ f’ọmobinrin. Bẹẹ na lo ti ṣe ifilọlẹ ajọ iranwọ tirẹ to pe ni ‘Garden of Peace’.
Yasmina Benslimane, Morocco
Oludasilẹ Politics4Her
Yasmina Benslimane lo fara rẹ jin fun imudọgba akọ ati abo. Oun ni oludasilẹ Politics4Her to n ṣe agbatẹru obinrin ati ọdọbinrin yoo ṣe maa kopa ninu oṣelu ati ohun to nii ṣe nipa igbe aye wọn.
Nigba iṣẹlẹ ilẹ riri waye lorilẹ-ede rẹ, Morocco, loṣu kẹsan ọdun yii, Benslimane ati ajọ rẹ pe fun iranwọ ti yoo maye dẹrun fawọn obinrin.
O ṣe atẹjade kan to ṣafihan awọn ipenija ti obinrin ati ọdọbinrin n doju kọ leyi ti ajalu naa yoo tunbọ jẹ ko buru sii, bii oṣi ati ifipafinifọkọ.
Gẹgẹ bii olutọni, olugbanilamọran ati ọmọ igbimọ adari lawọn ẹgbẹ ati ajọ to pọ,Benslimane maa n ran awọn ọdọbinrin lọwọ lati ṣe awari ati idagbasoke iwa adari laye wọn. Iṣẹ rẹ ti mu ko gba ami-ẹyẹ fun igbelarugẹ alaafia lawujọ awọn obinrin latọdọ ajọ UN.
Yael Braudo-Bahat, Israel
Ajafẹtọ alaafia ọmọniyan
Gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ adari ẹgbẹ ‘Women Wage Peace (WWP), Yael Braudo-Bahat mu imọ rẹ nipa eto ofin lo ninu ẹgbẹ to n pe fun alaafia ni Israel, leyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn le ni ẹgbẹrun lọna aadọta.
Ẹgbẹ WWP ti wọn da silẹ lọdun 2014 lo n wa ojuutu lọna oṣelu si laasigbo to n waye laarin Israel ati Palestine, ti wọn si n tẹmpẹlẹ mọ ojuṣe awón obinrin ninu igbesẹ alaafia.
Lati ọdun meji sẹyin ni WWP ti n darapọ mọ ẹgbẹ bii tirẹ kan ni Palestine taa mọ si ‘Women of the Sun’.
Braudo-Bahat wi pe oun bu ọla to pọ fun ẹni to fi ẹsẹ oun le ilana yii to si tun jẹ ẹnikeji ti wọn jọ da WWP sile, Vivian Silver, lẹni to lo ọpọlọpọ igbesi aiye rẹ jin fun mimu alaafia jọba ati irẹpọ wa laarin awọn ọmọ Israel ati Palestine. Silver lo padanu ẹmi rẹ ninu akọlu ti Hamas ṣe ni ọjọ keje oṣu kẹwa ọdun 2023.
Alicia Cahuiya, Ecuador
Ajafẹtọọ Iṣẹdalẹ ẹni
Gẹgẹ bii èèkàn ninu awọn to n ja fun igbo Iṣẹmbaye Ecuador, Alicia Cahuiya ṣe aṣeyọri to laami-laaka lọdun yii.
Manigbagbe ibo kan waye loṣu kẹjọ, awọn eeyan Ecuador dibo lati fopin si gbigbẹ kannga epo rọbi tuntun nibudo apapọ wọn ti wọn n pe ni Yasuní National Park. Ipinnu wọn yii tumọ si pe ileeṣẹ ijọba to n gbẹ epo nilẹ naa yoo fopin si iṣẹ rẹ nibi to jẹ ọkan ninu awọn agbegbe to kun fọfọ fun iṣẹ Ẹlẹdaa ju lọ, to si tun jẹ ibugbe fun ọpọ eeyan ti wọn ta kete, ti wọn n da ile aye wọn ṣe.
Cahuiya ti wọn bi ni Yasuní to si tun jẹ olori ẹgbẹ Waorani nation (NAWE), ti n ṣe ipolongo ayipada fun ọdun mẹwaa kọja.
Lọwọlọwọ, oun ni olori awọn obinrin nibi ipade apapọ awọn ọmọbibi Ecuador.
Ayipada oju ọjọ ti mu ki nnkan yatọ fun wa, o n fa ikun omi to n ba nnkan oko wa jẹ. Nigba ti oorun ba mu ju, t’ọgbẹlẹ de, pupọ ninu ounjẹ wa lo maa n ṣofo, eyi to maa n ba wa ninu jẹ lọpọlọpọ, nitori gbogbo igbiyanju wa lati ko ere oko ma n ṣegbe lojuu wa.
Alicia Cahuiya
Amal Clooney, UK/Lebanon
Amofin ẹtọ ọmọniyan
Amal Clooney jẹ agbẹjọro ẹtọ ọmọniyan ti o gba ami-ẹyẹ, ti o si ti lo ogun ọdun sẹyin lati gbeja awọn eeyan ti wọn fi ọwọ ọla gba loju.
O le iwaju awọn ẹjọ to lagabra, to si niiṣe pẹlu iwa odaran tako ọmọniyan ni Armenia ati Ukraine, pẹlu iwa ifipabanilopọ si awọn obinrin ni Malawi ati Kenya.
Lara awọn aṣeyọri to ṣe laipẹ ni bi o ṣe ṣoju ẹni ti awọn alakatakiti ẹṣin Islam ati ologun Darfur ṣe ikọlu si. O ti ṣe iranlọwọ lati mojuto itusilẹ awọn akọroyin ati awọn ẹlomii to wa ni atimọle oṣelu ninu iṣejọba awọn aninilara.
O jẹ Ọjọgbọn ni ile ẹkọ imọ ofin, 'Columbia Law School', ati ọkan lara awọn oludasilẹ 'Clooney Foundation for Justice', ajọ awọn amofin to n ṣiṣe amofin l'ọfẹẹ lati se iranwọ fun awọn eeyan ti awọn alagbara yanjẹ ni awọn orilẹede ti o le ni ogoji.
Dehenna Davison, UK
Ọmọ ile igbimọ aṣofin
Ni ọdun 2019, Dehenna Davison di aọfin akọkọ lati ẹgbẹ Conservative ti yoo ṣoju ẹkun Bishop Aucklandlati ọdun 1885 ti wọn ti da ẹkun idibo naa silẹ. Lọdun 2022 lo di minisiter fun idọgba igbe aye takọtabo. O gba oju mọ igbega awujọ ati isọdọtun ẹda.
Loṣu kẹsan an ọdun 2023 lo kọwe fi ipo minisita silẹ,lẹyin to fọnrere aisan ẹfọri tuulu (Migraine).
Nigba ti Davison di ọmọ ọdun mẹtala, wọn fi ẹṣẹ kan ṣoṣo pa baba rẹ, eleyi lo si mu ki o ṣẹri wọ agbami oṣelu. O da ẹgbẹ All-Party Parliamentary Group silẹ lati gbogun ti gbọnmọgbọnmọ iwa ipa fifi ẹṣẹ kan pa eniyan ati ipolongo pẹlu ajọ One Punch UK fun idajọ ododo ati atunto eto iṣedajọ lori rẹ.
Bakannaa lo tun gbajumọ mimu itẹsiwaju ba itọju aisan ẹfọri tuulu, ati ipolongo fun alekun owoona fun iwadii ijinlẹ nipa arun jẹjẹrẹ inu ọmu.
Christiana Figueres, Costa Rica
Ajafẹtọọ ayipada oju ọjọ ati aṣoju orilẹ-ede
Nigba ti ohun gbogbo dojuru nibi ipade apero ajọ iṣọkan agbaye lori ayipada oju ọjọ to waye ni Copenhagen ni ọdun 2009 ni wọn gbe Christiana Figueres wa lati wa wa ojutuu siṣoro naa.
Lẹyin ti wọn yan Figueres gẹgẹ bii akọwe agba fun ipagọ ajọ iṣṣokan agabye lori ayipada oju ọjọ ni o lo ọdun mẹfa gbako lati fi ṣeto idagbasoke awọn orilẹ-ede agbaye lati fẹnuko lori ọna abayọ si iṣoro ayipada oju ọjọ.
O to igba orilẹ-ede ti wọn gab lati buwọlu iwe adehun naa latari iṣẹ takuntakun to ṣe ni Paris lọdun 2015. Adehun yii ni wọn ti fẹnuko pe wọn ko ni jẹ ki ooru oju ọjọ mu ju iwọn ’20 degreee celsius’ lọ.
Figueres lo pawọpọ lati da Global Optimism silẹ. Ajọ naa n ṣiṣe papọ lati wa awọn ojutuu to rọrun lati fi yanju iṣoro ayipada oju ọjọ.
Nigba mii, o maa n ka mi laya ti inu mi si maa n bajẹ, ni igba mii kẹ inu maa n bi mi ni ṣugbọn ni ọpọ igba ni mo maa n lo ibanujẹ ọkan mi lati wa ojutuu si iṣoro yii lagbaye, ki n si rii pe agbaye dun sii fun awọn ọmọde ati iran to m bọ lọjọ iwaju.
Christiana Figueres
Bella Galhos, East Timor
Ajafẹtọ lori ọrọ oṣelu
Akikanju ajafẹtọ, Bella Galhos ti n ko ipa pataki ninu ayipada ilu East Timor - eyi ti awọn eeyan tun mọ si Timor-Leste - ṣaaju ki wọn to gba ominira lọwọ Indonesia lọdun 2002 ati lẹyin ti wọn gbaa tan.
Laarin ọdun ti o di ero eyin odi, Bella rin irinajo kaakiri agbaye lati ja ija ominira fun awọn ara ilu rẹ. O pada sile ni East Timor lẹyin ti wọn gba ominira lati kopa ninu kikọ ilu naa ti ilaji rẹ ti di alaini nitori laasigbo ti won koju fun ọpọlọpọ ọdun.
Lọdun 2015, o da ile ẹkọ Leublora Green School silẹ lati ṣe ipolongo idagbasoke ati lati ṣatilẹyin fun awọn ọmọde lati jẹ aṣojuu ayipada rere.
Lọwọ lọwọ, Galhos n ṣiṣẹ gẹgẹ bi oludamọran fun aarẹ ilu East Timor, ti o si n moju to riro awọn obirin lagabara nipa ọrọ aje, o si tun jẹ ajafẹtọ awọn eeyan LGBTQ+
Rina Gonoi, Japan
Ọga ologun tẹlẹ ri.
Nigba to wa lọmọ ọdun mọkanla lawọn ọmọ ogun obinrin Japan doola ẹmi Rina Gonoi lasiko ilẹ ririati tsunami ọdun 2011.
Lati igba naa lo ti ni lọkan lati darapọ mọ awọn ọmọ ogun obinrin Japan. O pada di ọmọ ogun ṣugbọn ireti rẹ di asan nigba ti awọn ọga ọkunrin kan n fi ibalopọ lọ lojojumọ.
O kẹru kuro nidi iṣẹ ologun lọdun 2022 to si bẹrẹ ipolongo eyi to ni ki wọn pe awọn ọga ologun ọkunrin to n dẹyẹ si awọn obinrin lati wa foju wina ofin.
Ipolongo rẹ yi ṣokunfa ki ileeṣẹ ologun ṣe iwadii to si ṣafihan ẹsun ọgọrun tawọn obinrin gbe wa tako awọn ọga ologun ọkunrin. Ileeṣẹ ologun pada fi iwe ti wọn ti tọrọ aforijin lọdọ Gonoi sọwọ si.
Sonia Guajajara, Brazil
Minisita ipinlẹ
Sonia Guajajara jẹ ọkan lara awọn to n ja fun ẹtọ awọn ọmọ onilẹ ni Brazil, lọdun 2023, o di minisita akọkọ fun ẹya awọn ti wọn fi ori wọ sọlẹ sibẹ, eyii ti Aarẹ tuntun, Lula da Silva gboriyin fun.
O ṣe ipinnu lati gbogun ti iwa ọdara lodi si ayika.
Ilu Araribóia ni wọn bi si lagbegbe Amazon, awọn obi Guajajara ko si kawe rara, ibẹ lo ti kọ nipa akoba ti ayipada oju ọjọ n ṣe si ayika.
Guajajara kuro nibẹ lati kawe nipa imọ ‘literature,’ o ṣiṣẹ nọọsi ati olukọ ko to tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ ajafẹtọ. Lọdun 2022, oun ni obinrin aṣofin akọkọ to wa lati agbegbe São Paulo.
A ni lati wa ọna ti a maa fi ṣe igbeleke ọrọ ayika ki a si gbogun ti ohun ti yoo maa pa ayika lara nitori awọn to yẹ ko maa daabo bo ayika naa ni yoo fara gba julọ ti iṣoro ọrọ ayika ba bẹrẹ. Awa ọmọ onilẹ gan ni ọrọ kan lati daabo bo ayika wa.
Sonia Guajajara
Renita Holmes, US
Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ibùgbé
Ìyá àfin Renita Holmes tó jẹ́ olùgbé Miami ni olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ OUR Homes, ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ilé kíkọ́ ní Florida, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Ó máa ń jà fún ẹ̀tọ́ lórí wíwá ibùgbé fún àwọn ènìyàn tó ń gbé nínú ìlú tí ìjọba kò bá ṣe tó fún wọn níbẹ̀, tó fi mọ́ àwọn tí àyípadà ojú ọjọ́ ń ṣàkóbá fún, tí owó ilé sì ń gbé ẹnu sókè.
Holmes, tó dàgbà sọ́wọ́ ìyá rẹ̀ nìkan pẹ̀lú ọmọ mọ́kànlá, jẹ́ àkàndá ẹ̀dá.
Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Cleo Institute Empowering Resilient Women, ẹgbẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyípadà ojú ọjọ́ nípa lílo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ó máa ń ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ilé iṣẹ́ tó ń kọ́ ilé lórí ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti Amẹ́ríkà àti ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ti àwọn obìnrin.
Ìrètí wà nínú ṣíṣe àwárí ìsopọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí obìnrin pẹ̀lú ìṣẹ̀dálẹ̀ wa. A ní agbára, ìfarajìn, a máa ń ṣe ìtọ́jú, a sì máa ń mú iṣẹ́ ṣe.
Renita Holmes
Sepideh Rashnu Iran, Iran
Onkọwe ati Olorin
Sepideh Rashnu di olokiki ni Iran fun atako rẹ si awọn ofin hijab wiwọ ni dandan.
Lẹyin awuyewuye to waye ninu ọkọ ayọkẹle kan pẹlu obinrin kan to n fipa mu ki wọn maa bori, wọn mu un.
Ni akoko ti o wa ni atimọle, o farahan lori Tẹlifisan ijọba pẹlu apa ni oju rẹ, “ti o si tọrọ aforijin” fun ihuwasi rẹ. Eyii waye ni oṣu keje ọdun 2022, ni ọsẹ diẹ ṣaaju ki Mahsa Amini, ọmọ ọdun 22 to ku lasiko ti o wa ni atimọle ọlọpaa to n fi ofin de iwa ti ko tọ ni Iran.
Ni ibẹrẹ ọdun yii, kele ofin gbe Rashnu lẹyin ti o pin awọn fọto ara rẹ lori ayelujara lai bo ori. O sọ pe wọn ti da oun duro ni fasiti nitori ijafẹt'ọmọniyan rẹ.
O ti jade kuro ni atimọle lọwọlọwọ bayii, o si n tẹsiwaju lati tako awọn ofin hijab wiwọ ni dandan.
Nataša Kandić, Serbia
Agbẹjọro ati Ajafẹtọmọniyan
Lati igba ti ija ti bẹ silẹ ni orilẹede Yugoslavia tẹlẹ lọdun 1990s, Natasa Kandic ṣe akọsilẹ awọn iwa ọdaran to waye lasiko ogun bi ifipabanilopọ, ifiyajẹni, iṣekupani ati fifi tipa tipa sa kuro.
O ṣe aṣoju fun ọpọlọpọ mọlẹbi to lugbadi isẹlẹ yii niwaju ileẹjọ to n gbọ ẹsun nipa ogun ni Belgrade, to si wa lara igbimọ to ṣe ofintoto ilana ti ijọba aarẹ Serbia labẹ Slobodan Milosevic gbe kalẹ fun Kosovo.
Kandic ni oludasilẹ ileeṣẹ ‘Humanitarian Law Center’, to si ma gba oriyin ni ọpọ igba fun bi ko ṣe ki n se magomago ninu awọn iwadii rẹ fun ẹsun ogun.
O ṣe igbọwọ lati se eto RECOM Reconciliation Network, eyi to n gbero lati fidi awọn nnkan ohun to waye ni Ogun Balkan, nibi eeyan toto 130,000 ti jade laye
Rukshana Kapali, Nepal
Oluponlogo fun ibugbe
Rukshana Kapali jẹ ọkan lara awọn ọmọ onilẹ Newa nilu Nepal, o tun jẹ akọ to di abọ to n ja fun etọ ọmọniyan ti o si ni ipenija idaraenimọ lọmọkekere nitoripe ko ri alaye pipe.
O bẹrẹ irinajo idanilẹkọ ara rẹ nipa ọrọ eya akọ tabi abo ati lori ibasepọ. O safihan ara rẹ gẹgẹ bi akọ to n se bi abọ lọdọmọde, latigbana lo ti n ja fun ẹto awọn eeyan bi tirẹ.
ọdun kẹta rẹ ree gẹgẹ bi akẹkọọ ọrọ ofin ni ifasiti to si n kopa ninu eto ilosiwaju fun ẹtọ awọn eeyan LGBTQ+ nilẹ Nepal.
Kapali wa lati ẹya Jugi laarin awọn eeyan Newa ti iwe itan fi lelẹ pe wọn ya sọtọ ti wọn si doju ija kọ awọn ti wọn fe fi ipa le wọn kuro nilẹ iran wọn.
Sofia Kosacheva, Russia
Sofia Kosacheva je onijo-lorin to tun n kọ awọn akẹkọọ ko to tun padeawọn to n ṣiṣẹ panapana lọdun 2010.
Oun funra rẹ di panapana to si bẹrẹ si ṣeto kikọ agbegbe to ti n kọ awọn eeyan ni iṣẹ panapana lati ran awọn eeyan orilẹ-ede Russia lọwọ.
Eyi bi eso rere ikọ panapana to le ni mẹẹdọgbọn kaakiri orile-ede Russia.
Ọpọlọpọ ina igbo ọba ni wọn ti pa lasiko ni Russia ko to darapọ mọ Greenpeace to jẹ ajọ ti kii ṣe ti ijọba ki wọn to sọ ajọ naa ni orukọ ’Undesirable Organaisation’ ti wọn si ti ẹka ti Russia pa nigba to ya.
Kosacheva tun ṣe itakun agbaye lori ayelujara nibi ti wọn ti n pese iye ati ifitonileti nipa awọn ina to n jo ni Russia pẹlu ọna lati fopin si ina naa.
Ko si bi iṣoro ayipada oju ọjọ se pọ to, ibi pẹlẹbẹ ni a ti n mu ọọlẹ jẹ ni ọna abayọ diẹdiẹ. O le dabi pe ipa ti a n ko yi keere ni agbaye ṣugbọn a n mu ayipada rere ba agbegbe wa.
Sofia Kosacheva
Monica McWilliams, United Kingdom
Oloṣelu nigba kan ri to tun n fọn rere alaafia lawujọ
Ọdun yii lo pe ọdun mẹẹdọgbọn ti wọn buwọlu iwe adehun ‘Good Friday’ ni agbegbe Northern Ireland. Monica Williams jẹ ọkan lara awọn oloṣelu to ko ipa pataki julọ ninu ijiroro to ja si adehun alaafia naa.
Oun ati awọn kan ni wọn pawọpọ da ẹgbẹ oṣelu Northern Ireland Women’s Coalition silẹ. Egbẹ oṣelu yii kaakiri ẹkun naa to si ṣafihan ipese laafia ninu adehun gbogbo.
Wọn yan McWilliams sipo gẹgẹ bii kọmiṣọnna agba to n ja fẹtọọ ọmọniyan ninu ile igbimọ aṣofin agba akọkọ ti orilẹ-ede Northern Ireland. Oun lo kọkọ kọ abadofin ẹtọ awọn eeyan Northern Ireland
Lọwọlọwọ, McWilliams ni kọmiṣọnna fun awọn ọmọ ogun ti wọn yọ kuro to si ti gbe iwe to pọ jade lori gbigbogunti ifiyajẹ awọn obinrin ni awujọ.
Najla Mohamed-Lamin, Western Sahara
Ajafẹtọọ awọn obinrin ati oju ọjọ
Oludasilẹ ibudo ikawe Almasar, Najla Mohamed-Lamin fẹ kọ awọn obinrin ati awọn ọmọde lẹkọọ nipa ilera ati ayika, ni ibugbe ogunlende to wa ni Saharawi, eyi to wa ni Guusu-Iwọ-Oorun Algeria.
Iwọ-Oorun Sahara gan-an lawọn ẹbi rẹ ti ṣẹ wa, eyi to jẹ agbegbe kan ti ijọba ilẹ Spain n paṣẹ rẹ tẹlẹ, ti Morocco gba ni 1975 ti wọn si ti n fa ọrọ ija ilẹ ibẹ lọdun pipẹ. Ọrọ naa lo le awọn ẹbi Lamin kuro nile wọn, wọn di ero ẹyin odi pẹlu ipá, ki wọn ma baa koju ijamba.
Ibudo ogunlende ni wọn bi Mohamed -Lamin si ti wọn si ti wo o dagba, o kọ ede oyinbo nigba to di ọdọmọbirin, o si n ṣe ogbufọ fawọn aṣoju lati ilẹ okeere, o si pada dẹni to kawe niluu oyinbo pẹlu iranlọwọ ọpọ eeyan to dawo ileewe rẹ jọ fun un.
Lẹyin to kawe gboye ninu imọ nipa idagbasoke ati ọrọ awọn obinrin, Lamin pada si ibudo ogunlende to ti kuro, lati ṣe iranlowo fun ẹgbẹrun lọna igba eeyan ti wọn jẹ Saharawi, lati pese omi ati ounjẹ, eyi ti ayipada oju ọjọ ti jẹ ko tun nira si i fun wọn.
A gbọdọ koju ipa ti ayipada oju ọjọ n ni lawọn agbegbe Aṣálẹ̀, eyi to n ba awọn ibugbe wa jẹ pẹlu ìkún omi, iji lile to n fẹ iyẹpẹ, ti awọn eeyan wa si n jiya labẹ inira ooru abi ọrinrin lile. Gbogbo eleyi si n ṣẹlẹ botilẹjẹwipe awọn eeyan wa ko lọwọ ninu iṣoro ayipada oju ọjọ yii.
Najla Mohamed-Lamin
Ulanda Mtamba, Malawi
Olugbogun ti fifi ọmọde f'ọkọ
Ulanda Mtamba dagba ni ileto kan ni Lilongwe, lorilẹ-ede Malawi, nibi ti ko ti si atilẹyin fun ẹkọ awọn obinrin, leyi to mu ki ọpọlọpọ o file-ẹkọ silẹ lati lọọ lọkọ lai tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun.
Mtamba lo pe irufẹ aye yii nija, to si rii pe oun kẹkọ gboye ‘Master’s’ lẹyin to ṣetan ni fasiti.
O n ṣe ipolongo fun amulo awọn ofin to daabo bo awọn ọdọbirin tako igbeyawo laitọjọ ati ki wọn moju to awọn ipenija ilera to rọ mọ oyun nini ni kekere.
Lọwọ yii, Mtamba ni adari ‘AGE Africa’ ni Malawi, iṣẹ ajọ naa si ni lati rii pe awọn ọdọbirin naa ni anfani lati wọ ile-ẹkọ girama bii awọn ọkunrin naa jakejado ilẹ adulawọ.
Tamar Museridze, Georgia
Akọ̀ròyìn
Òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán Tamar Museridze - tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Tamuna - jẹ́ gbajúmọ̀ nídìí iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Georgia láti ìgbà tó ti wà ní ọmọ ọdún méjìdínlógún. Àmọ́ ìgbé ayé yí padà gidigidi nígbà tó pé ọmọ ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n lẹ́yìn tó mọ̀ pé wọ́n gba òun tọ́ ni.
Ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tì láti wá àwọn òbí tó bi gan-an tí èyí sì tú àṣírí bí àwọn ènìyàn ṣe ń gba ọmọ tọ́ lọ́nà àìtọ́ èyí tó ti ń wáyé ní Georgia láti ọdún 1970.
Ó dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ lórí Facebook tó pé orúkọ rẹ̀ ní "I'm searching" tó túmọ̀ sí "Mò ń wá" ní èyí tó fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí gbígba àwọn tọ́ lọ́nà àìtọ́ tó ń wáyé lórílẹ̀ èdè náà pàápàá ní àwọn ilé ìwòsàn ìgbẹ̀bí.
Àjọ Museridze ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn ẹbí wọn àmọ́ òun kò ì tíì àwọn ẹbí rẹ̀ títí di àsìkò yìí.
Neema Namadamu, Democratic Republic of Congo
Ajafẹtọ awọn akanda
Ajọ Hero Women Rising (abi Mama Shuja) ni o n gbiyanju lati mayedẹrun fun awọn obinrin ati ọdọbirin ni DRC.
Ajafẹtọ awọn akanda Neema Namadumu lo da ajọ yii silẹ to si n eto ẹkọ ati imọ-ẹrọ lati sọrọ nipa igbe aye awọn obinrin ati lati jẹ ki wọn mọ ẹtọ wọn.
Wọn bi Namadumu ni ileto kan lapa ila-oorun Congo. O ni arun ‘polio’ nigb to wa lọmọ ọdun meji. Oun si ni akanda akọkọ lati lati ẹya rẹ ti yoo jade ile-ẹkọ fasiti.
O di ọmọ ile aṣofin o si tun ti jẹ olubadamọran fun minisita fọrọ awọn obinrin ati idile.
Michelle Obama, US
Agbẹjọro, olukọtan ati oluponlogo
Aya aarẹ tẹlẹ lorilẹede Amẹrika, Michelle Obama jẹ oludasilẹ ajọ ‘Girls Opportunity Alliance’, eyi to n se atilẹyin fun awọn ileeṣẹ iranwọ ẹsẹkuku to n sisẹ lati ri pe awọn ọdọmọbinrin ri ẹkọ to pe gba.
Eyi lo da lori eto ‘Let Girls Learn’, eto kan ti Obama da silẹ lasiko ro wa nipo gẹgẹ bi aya aarẹ eyi to lo ilana ijọba lati pese anfani lati ran awọn ọdọmọbinrin lọwọ kaakiri lati le ri eto ẹkọ to peye gba.
Gẹgẹ bi aya Aarẹ, o ṣe agbatẹru eto nla mẹta mii: ‘Let’s Move!’ to wa fun pi pese iranlọwọ fun awọn obi lati le tọ ọmọ wọn pẹlu ileri to peye; ‘Joining Forces’ eyi to wa lati ṣe iranwọ fun ọmọ ileeṣẹ ologun Amẹrika, agba ọjẹ ni ilu ati mọlẹbi wọn; ati ‘Reach Higher’- eyi to si n se di oni – ri rọ awọn ọdọ lati gbajumọ eto ẹkọ.
Bernadette Smith, Turtle Island / Canada
Agbẹnusọ fawọn teeyan wọn sọnu
Latari bi aburo rẹ (Mi o mọ boya aburo ni tabi ẹgbọn, sister lasan ni wọn kọ. Please, note sir) ṣe di awati lọdun 2008, Bernadette Smith ko sinmi ninu igbiyanju rẹ lati mọ ohun to fa a tọmọ naa fi sọnu bẹẹ lai ri i mọ.
O di agba-ọjẹ agbẹnusọ fawọn ẹbi tọmọ wọn obinrin atawọn agbalagba obinrin wọn sọnu, tabi ti wọn pa jakejado Canada, o si gbe igbimọ kan kalẹ lati maa ṣakoso, ki wọn si maa wadii ohun to n ṣẹlẹ gan-an.
Bakan naa lo jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ajọ kan ti wọn pe ni ‘Drag the Red, eyi to maa n wo inu odo pupa to wa ni Winnipeg, boya awọn yoo ri oku eeyan abi apẹẹrẹ kan to n tọka sawọn to sọnu.
Laipẹ yii ni wọn yan Smith fun igba kẹta gẹgẹ aṣofin nile igbimọ Manitoba, eyi jẹ ko fitan balẹ bii ọkan ninu awọn obinrin akọkọ ti wọn yan lagbegbe naa. Lọwọlọwọ, oun ni alakooso fun ọrọ ile gbigbe, ọrọ awọn ti iwakiwa ti di baraku fun ati tawọn alai-rilegbe.
Iryna Stavchuk, Ukraine
Olubadamọran nipa ọrọ oju ọjọ
Oloṣelu nipa ọrọ oju ọjọ, Iryna Stavchuk darapọ mọ ajọ European Climate Foundation lẹnu ọjọ mẹta yii gẹgẹ bii aṣoju orilẹ-ede Ukraine pẹlu erongba lati ṣeto to tọ nipa anfani ojo ọjọ lorilẹ-ede rẹ lẹyin ti ogun to n lọ lọwọ nibẹ ba pari.
Ṣaaju asiko yii, o ṣiṣẹ fun ijọba Ukraine gẹgẹ bii igbakeji minisita fun ọrọ ayika lati ọdun 2019 si ọdun 2022.
Stavchuk wa lara awọn to da ajọ ti kii ṣe ijọba meji silẹ, iyẹn Ecoaction ati Kyiv Cyclists' Association (U-Cycle), o si ti ṣe ọpọ iwuri fun awọn ẹgbẹ to n ja fun ọrọ ayika ati oju ọjọ loriṣiriṣi.
Ojuṣe wa ni lati ṣe iwọn ti a le ṣe ni gbogbo ipo ti a ba wa. Ọrọ Saint Francis ti Assisi to sọ pe “Bẹrẹ si ni ṣe awọn ohun to yẹ, lẹyin naa ṣe awọn ohun to rọrun lati ṣe; lojiji ni o maa ri pe o ti n ṣe awọn ohun to ṣoro lati ṣe” ni mo n tẹlẹ.
Iryna Stavchuk
Gloria Steinem, US
Aṣiwaju ajafẹtọ awọn obinrin
Gẹgẹ bi oludari ẹgbẹ to n pe fun idọgba laarin ọkunrin ati obinrin lagbaye lati awọn ọdun 1970, ipa ti Gloria Steinem ko ninu agbekalẹ ẹtọ awọn obinrin ti di nnkan ti gbogbo aye mọ fun ọpọlọpọ ọdun.
Steinem ti ṣiṣẹ lori awọn ọrọ to niiṣe pẹlu idọgba laarin akọ ati abo, gẹgẹ bii Ajafẹtọmọniyan, Akọroyin, Onkọwe ati Agbẹnusọ fun igbohunsafẹfẹ.
O jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ iwe iroyin 'MS. Magazine' ti o kọkọ jade l'ọdun 1971, ti o si wa l'ode titi di asiko yii, ti awọn eeyan n gbe yẹwo gẹgẹ bii iwe iroyin akọkọ to ṣe afihan etọ ati ipenija to n koju awọn obinrin.
Ni ẹni ọdun mọkandinlaadọrun, Steinem tẹsiwaju iṣẹ rẹ si agbaye nipasẹ atilẹyin rẹ fun awọn ojulowo ajọ bii, 'Women's Media Center, the ERA Coalition ati Equality Now'.
Summia Tora, Afghanistan
Ajafẹtọ awọn aṣatipo
Ajo Dosti Network jẹ ajọ kan to fi ara jin funipese awọn ohun elo ati iroyin to ṣe koko fun awọn eeyan orilẹede Afghanistan – yala awọn to n gbe ni orilẹede Afghanistan tabi awọn to n ṣe atipo nibẹ -, ri wọn da silẹ lẹyin ti awọn ọmọ ikọ Taliban gba ijọba lọdun 2021.
Gẹgẹ bi ẹni ti oun funrararẹ ti ṣe atipo ri, oludasilẹ ajọ naa, Summia Tora mọ awọn ipenija ti awọn ogunlende n koju.
Eto ifinimọle fun awọn aṣatipo ati bi awọn akẹkọọ ti ogun sọ di alarinkiri ṣe le janfani eto ẹkọ ni awọn nnkan to gbajumọ.
Gẹgẹ bi ẹni to mọ agbara isọdọtun to wa ninu ẹkọ to ye kooro, Tora ti ṣiṣẹ pẹlu awọn ajọ bii ajọ iṣọkan agbaye, UN ati banki agbaye, ajọ iṣuna Malala fund ati Schmidt Futures. Nipasẹ ajọṣepọ wọnyii lo fi n ṣe agbatẹru ipese ẹkọ to ye kooro fun awọn aṣaripoati awọn obinrin ati ọdọmọbinrin to bọ ha sinu awọn rogbodiyan nibẹ.
Xu Zaozao, China
olupolongo ki obinrin ma fi ẹyin ibimọ pamọ
Ni ọdun 2018,o gbiyanju lati fi ẹyin ibimọ rẹ pamọ ni ileewosan ijọba kan ni Beijing. Amọ wọn sọ fun Xu Zaozao, ẹni ti ko ni ọkọ wí pe awọn to wa nile ọkọ nikan leto yi wa fun lorilẹede China
O wọ ileewosan naa lọ sile ẹjọ níbi ti igbẹjọ akọkọ iru rẹ lori fifun awọn ti ko si nile ọkọ lanfaani ati fi ẹyin ibimọ wọn pamọ ni China.
Igbẹjọ yi to bẹrẹ loṣu Kejila ọdun 2019 di ilumọọka tohun ti bi awọn eeyan ṣe n gbarata lori bi awọn to n bimọ ni China ko ṣe pọ.
Idajọ igbẹjọ yi ko ti jade ṣugbọn ọrọ Xu jẹ nkan tàwọn onimọ ẹka ofin, Iṣegun ati ẹtọ n gbe yẹwo. Lonii, Xu jẹ gbajugbaja ajafẹtọ obinrin lori ọrọ ibimọ fawọn obinrin ti ko ni ọkọ.
Sayẹnsi, Ilera ati Imọ ẹrọ
,
Oniṣowo nipa nkan abalaye ti a n lo fun ile kikọ
Lọdun 2014 nigba ti awọn alakatakiti Islamic State gba ọpọ ilẹ to wa ni orilẹ-ede Raq ni Basima Abdulrahman dide. Basima kẹkọọ imọ oye giga ni Fasiti kan ni orilẹ-ede America.
Ọpọ ilu ni orilẹ-ede Iraq ni wọn bajẹ nibi ikọlu to waye naa ṣugbọn nigba ti Abdulrahman pada sile lati America lẹyin to kọ ẹkọ sii nipa imọ ile kikọ lo pinnu lati ran awọn eniyan rẹ lọwọ.
Basima da ajọ KESK silẹ, ajọ yii ni alakọkọ iru rẹ to n ṣamulo ohun ikọle abalaye. O ṣawari pe o san lati maa pese ohun eelo abalaye lati fi kọle ni eyi to n lo papọ pẹlu ohun eelo amuṣagbara pẹlu awọn nkan adayeba to wa fun ile kikọ ni Iraq.
Abdularahaman ni oun n risi i pe awọn ile ti wọn n kọ lasiko yii ni Iraq ko ni ṣakoba fun awọn iran to m bọ.
Ọpọ igba bi mo maa n ni ifoya nipa iṣoro ayipada oju ọjọ ti mo si maa n woye bi eeyan ṣe le ni igbe aye alaafia lai ṣafikun si iṣoro yii ati pe lati wa ọna abayọ sii.
Izabela Dłużyk , Poland
Agbohunsilẹ
Pẹlu ẹro igbohunsile lowo rẹ, Izabela Dluzyk ma n lo kiri inu igbo adayeba Białoweiza ni Europe lati gba awon ohun ara-oto to wa nibe sile.
Agbohunsilẹ yii jẹ eeyan ọtọ, yatọ si pe o jẹ ọdọmọdebirin to n ṣe iṣẹ ti awọn ọkunrin yan laayo, amọ nitori wọn bi ni afọju.
Lati igba ti awọn mọlẹbi rẹ ti fun ni ẹrọ agbohunsilẹ lọmọ ọdun mejila ni Dłużyk ti da ohun ẹyẹ mọ, o si le darukọ oniruru ẹya ẹyẹ to ba gbọ ohun wọn.
O gbagbọ pe anfani nla ni lati mọ riri iṣẹda.
Amina Al-Bish, Syria
Afarajin-oṣiṣẹ to n yọni ninu ewu
Bi ogun abẹle Syria ṣe n lagbara si i lọdun 2017, Amina Al-Bish pinnu lati jẹ ọkan ninu awọn eeyan to fi ara rẹ jìn lai gbowo lati maa yọ awọn ẹni tewu ba kan kuro ninu ijamba. Abẹ asia Syria Civil Defence ni wọn ti n ṣe eyi, eyi ti wọn tun n pe ni White Helmets, afojusun wọn ni lati da aabo bo ẹmi awọn araalu, ki wọn si ṣetọju akọkọ fawọn to ba farapa.
Amina tun fi ara rẹ silẹ lati maa gba awọn ti ilẹ-riri ba koju wọn kuro ninu iṣoro naa, iyẹn ilẹ riri to ṣẹlẹ ni Syria ati Turkey loṣu keji ọdun 2023, to ko awọn adugbo sidaamu, tawọn ẹbi tiẹ gan-an si ṣegbe sabẹ ilẹ to ri.
Ni bayii, Al-Bish n ṣiṣẹ lati mu ki igbesi aye awọn obinrin yooku l’Ariwa Syria rọrun si i. Awọn ibi ti ija ti n tẹsiwaju. O n kẹkọọ lati gboye ninu imọ nipa Okoowo ṣiṣe, o si ni afojusun oun ni lati lọwọ ninu agbekalẹ Syria alalaafia.
Sara Al-Saqqa, Agbegbe Palestine
Oniṣẹ abẹ
Obinrin akọkọ to gba iwe-ẹri gẹgẹ bii oniṣẹ-abẹ ni Palestine, dokita Sara Al-Saqqa n ṣiṣẹ nile-iwosan to tobi ju kọ lagbegbe naa, Al-Shifa.
Al-Saqqa lo n lo oju opo ‘Instagram’ rẹ lati ṣe akọọlẹ bo ṣe n tọju awọn eeyan laarin ogun. Ile-iwosan Al-Shifa lo ti bajẹ kọja ala ni bi awọn ọmọ-ogun Israel ṣe tẹsiwaju pẹlu ṣiṣe akọlu si ẹgbẹ Hamas.
Al-Saqqa lo n kọ nipa aisina, epo, omi ati ounjẹ, leyi to jẹ idinwọ fun ile-iwosan lati tọju awọn alaarẹ to wa nibẹ. Dokita naa lo kuro ni Al-Shifa nigba diẹ ṣaaju ki awọn ọmọgun Israel o too yawọ ibẹ ninu ti wọn wi pe wọn gbe tako ẹgbẹ Hamas.
Al-Saqqa lo kẹkọ gboye ninu iṣegun oyinbo ni Islamic University ni Gaza, to si kẹkọ iṣẹ-abẹ ni fasiti London's Queen Mary. Ọpọ awọn obinrin lo ti n tọ ipasẹ Al-Saqqa leyi to mu ki o ma jẹ ọkanlawọn oniṣẹ-abẹ mọ.
Bayang, China
Ẹni to n ṣe akosile oun to n ṣẹlẹ lojọ ati alagbawi fun imuduro ṣinṣin
Lati ọdun 2018, Bayang ti n tọju iwe-iranti-eco-diary, mimojuto awọn eya agbegbe ati awọn iyipada si awọn orisun omi, gbigbasilẹ oju ọjọ ati akiyesi awọn ohun ọgbin.
O ngbe ni Ilu Qinghai ti Ilu China, ti o wa ni Plateau Tibet ati pe o ti ni iriri awọn ipa ti iyipada oju-ọjọ gẹgẹ bi awọn iwọn otutu ti o ga julọ, awọn glaciers yo ati aginju.
Bayang jẹ apakan ti Sanjiangyuan Women Environmentalists Network, ati awọn agbawi ilera ati iduroṣinṣin ni agbegbe rẹ.
O ti ni awọn ọgbọn ni ṣiṣe awọn ọja ore-ọrẹ - pẹlu balm aaye, ọṣẹ ati awọn baagi - lati daabobo awọn orisun omi agbegbe ati gba awọn miiran niyanju lati darapọ mọ idi ayika.
Susan Chomba, Kenya
Onimọ Sayẹnsi
Susan Chomba ni adari World Resources Institute (WRI). O wi pe iya ti oun jẹ ni kekere lo mu ki oun o maa ran awọn eeyan lọwọ.
Idabobo awọn aginju, sisọ ilẹ di ọtun ati mimu ayipada rere ba ọrọ ounjẹ ni Africa lo jẹẹ logun.
Jakejado Africa ni Chomba ti n ba awọn agbẹ kekeeke ṣiṣẹ, paapaa julọ awọn obirin ati ọmọde, lati bawọn tun ilẹ wọn ṣe.
O si maa n fi imọ rẹ ran ijọba atawọn oluṣewadii lọwọ.
Aiṣe nkankan awọn oludari l'agbaye, paapajulọ awọn to jẹ ogbontaagi ẹni to n ko ijamba ba oju-ọjọ, awọn to jẹ wipe wọn ni agbara lati fi ọrọ aje mu ayipada wa ṣugbọn ti wọn fa sẹyin nitori owo, agbara and ọrọ oṣelu ma n kan mi lominu. Lati ma ṣafihan bo ṣe ri lara mi, mo ju ara sinu iṣẹ ṣiṣẹ pẹlu awọn obirin ati awọn ọdọ kaakiri ilẹ Afirika lati ṣe itọju ayika wa ati lati mu atunṣe ati ayipada ba awọn ọna ounjẹ wa.
Susan Chomba
Leanne Cullen-Unsworth, UK
Onimọ sayẹnsi nipa nkan ẹlẹmi inu omi
Koriko inu omi maa n gba awọn oorun kabọ-un ati pe o maa n pese ibugbe fawọn ẹja, amọ o ti mu iparun ba ọpọ nkan abẹmi ninu omi.
Leanne Cullen-Unsworth jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ati alaṣẹ iṣẹ lori koriko inu omi, eyi to jẹ akọkọ iru rẹ lorilẹede Uk.
Eto yii jẹ ko rọrun lati maa lo ẹrọ rimuutu lati gbin koro-irugbin ati lati ṣe iranwọ fun ọpọ orilẹede lati mu awọn koriko to wa labẹ omi pada bọ sipo.
Cullen-Unsworth to jẹ onimọ ijinlẹ pẹlu iriri to le ni ogun ọdun ninu iṣẹ iwadii nkan abẹmi inu omi fi ara rẹ jin si ṣiṣe imọ ijinlẹ ati da nkan si ati imupadasipo.
Eleyii pọju fun ẹnikẹni to ba fẹ danikan ṣe aṣeyege sugbọn awọn eeyan n darapọ ṣiṣẹ ti wọn si n ṣe ajọpin imọ. Ni iwọnba titemi, mo mọ wipe a le mu ajinde ba ibugbe pataki, ki a daaboboo, ki a si ṣe atunse rẹ fun gbogbo anfaani to n ṣe fun agbaye ati fun awujọ wa.
Leanne Cullen-Unsworth
Canan Dagdeviren, Turkey
Onimọ ijinlẹ Sayẹnsi ati Oludasilẹ nnkan
O jẹ ọjọgbọn ni ile ẹkọ Massachusetts Institute of Technology (MIT)'s Media Lab ni Amẹrika, Laipẹ yii ni Canan Dagdeviren ṣe idasilẹ ẹrọ to le sawari aarun jẹjẹrẹ ọyan
O lo iriri to ri gba lati lọdọ anti rẹ to lugbadi aarun jẹjẹrẹ ọyan to wa ni ipele to gbẹyin ni ẹni ọdun mọkandinlaadọta pẹlu bi o ṣe n ṣe ayẹwo aarun jẹjẹrẹ lorekore, to si dagbere faye lẹyin oṣu mẹfa.
Lẹgbẹ ibusun anti rẹ, Dagdeviren ṣe sawari agbekalẹ kan lati ṣe ẹrọ kan ti eeyan le fi si a bẹ kọmu, ti yoo maa fi ayesilẹ fun ayẹwo lorekore fun eeyan lati koju aarun jẹjẹrẹ ọyan. Imọ-ẹrọ yii le gba ọpọlọpọ miliọnu eeyan la.
Marcela Fernández, Colombia
Ẹni to n ṣamọna ni irin ajo
Glaciers n pese orisun omi fun awọn agbegbe ibilẹ, ṣugbọn ni Ilu Columbia wọn n tete parẹ.
Oludasile Marcela Fernández ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ ni NGO Cumbres Blancas (White Peaks) ṣe akiyesi lori ọrọ naa, to n ṣe afihan pe nine awọn glaciers mẹrinla to wa tẹlẹ, mẹfa nikan ni o kù ati pe awọn na wa ninu ewu.
Nipasẹ awọn irin-ajo imọ-jinlẹ ati nipa apejọ ẹgbẹ awọn to n gun oke-nla, awọn ayaworan, awọn onimọ-jinlẹ sayẹensi, ati awọn oṣere, Fernández ṣe abojuto awọn ayipada ati dagbasoke awọn ọna lati ṣe idiwọ pipadanu glacier.
Pẹlu iṣẹ akanṣe ti o wa, "Pazabordo" (Peace on Board), o tun rin irin-ajo lọ si awọn agbegbe ti o ni ikọlu ija nigba aadọta ọdun Colombia.
Awọn glaciers ti kọ mi lati koju ibinujẹ. Nigbati o ba gbọ wọn o mọ pe ipadanu wọn ma jẹ ibajẹ ti a ko le ṣe atunṣe, ṣugbọn a tun le ṣe alabapin lati fi ami silẹ.
Marcela Fernández
Timnit Gebru, Amẹrika
Akọṣemọṣẹ nipa AI
Timnit Gebru jẹ akọṣẹmọṣẹ ati onimọ ijinlẹ sayẹnsi nipa imọ kọmputa, oun ni oludasilẹ ati alaṣẹ ileeṣẹ Distributed Artificial Intelligence Research Institute (DAIR), ti wọn da silẹ gẹgẹ bii ileeṣẹ olominira.
O maa n bu ẹnu atẹ lu idẹyeṣi takọ-tabo lori ọrọ imọ ‘facial recognition,’ o si wa lara awọn to da ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba eyii ti kii ṣe idẹyẹsi awọn alawọ dudu ti wọn nifẹ si imọ AI.
Ọmọ orilẹ-ede Ethiopia naa wa lara awọn alaṣẹ ajọ AddisCoder, eyii to n kọ awọn akẹkọọ orilẹ-ede Ethiopia ni imọ ẹrọ ‘programming.’
Lasiko to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Google lọdun 2020, o wa lara awọn to kọ iwe kan nipa ede ti wọn fi n kọ AI ati idẹyẹsi awọn eeyan kan ti wọn ko lẹnu lawujọ.
Iwe naa wa lara idi to fi kuro nileeṣẹ ọhun, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ naa ni iwadii Gebru ninu iwe ọhun ko pe, ati pe oun funra rẹ lo kọwe fi ipo silẹ, amọ Gebru sọ pe ṣe ni ileeṣe naada oun duro.
Claudia Goldin, US
Onimọ nipa eto ọrọ aje to si tun ti gba ami ẹyẹ agbaye Nobel Prize
ọmọ Amẹrika ni, Onimọ nipa itan eto ọrọ aje ati onimọ ni eto ọrọ aje to nii ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ni Claudia Goldin. Oun lo gba ami ẹyẹ agbaye Nobel Prize fun ti imọ nipa eto ọrọ aje ni ọdun 2023 fun iṣẹ iwadi rẹ nipa eto igbanisiṣẹ awọn obinrin ati ohun to n ṣe okunfa aidọgba owo oṣu laarin awọn ọkunrin ati obinrin lẹnu iṣẹ.
Oun ni obinrin kẹta ti yoo gba ami ẹyẹ yii, bẹẹ si ni oun ni obinrin akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ naa laini pin in pẹlu ọkunrin.
Godlin di ipo Ọjọgbọn imọ nipa eto ọrọ aje mu ni fasiti Havard. Awọn ẹka imọ bii aidọgba ọwọ oṣu, eto ẹkọ ati iwọlewọde awọn eeyan si orilẹede ni iṣẹ iwadii rẹ si saba maa n da le lori.
Lara awọn akọsilẹ iwadi rẹ to di ilumọọka ni eyi to ti ṣe agbeyẹwo itan iriri awọn obinrin ninu ilepa iṣẹ oojọ ati gbigbe ẹbi ro, pẹlu ipa ti ogun ifetosọmọbibi nii kolori iṣẹ oojọ obinrin ati ipinnu wọn nipa eto igbeyawo.
Trần Gấm, Vietnam
Oniṣowo sisọ ẹgbin di afẹfẹ gaasi.
Ni ọdun 2012 Trần Gấm bẹrẹ si nii lo awọn ọna ohun amuṣagbara ti kii ṣe akoba fun ayika lawọn oko ni Vietnam.
Arabinrin ọlọmọ meji naa rii pe ipongbẹ wa fun ilana ohun amuṣagbara yii, o si bẹrẹ si ni ṣe okowo ohun elo ipese afẹfẹ gaasi lati ara ẹgbin ni ilu Hanoi, ki o to fẹ oju rẹ si awọn agbegbe mẹta to yii ka.
Eto yii ran ọpọ awọn agbẹ lọwọ lati din iye owo ti wọn n na lati yi igbẹ maluu ati ẹlẹdẹ, oṣibata at’awọn ẹgbin miran si afẹfẹ gaasi - eyi ti ọpọ ri gẹgẹ bi ọna amuṣagbara to durodeede ju ti epo rọbi- ku ti won si le e lo fun idana ati awọn ohun miran ninu ile.
Awọn okoowo bii ti Trần n ko awọn ileto jọ lati ṣe atilẹyin to yẹ fun didẹkun wahala oju ọjọ.
A gbọdọ gbe igbe aye to dara, nitorinaa mo ti gbiyanju lati daabo bo awọn ewyan mi nipa mimu ilera wọn durodeede nipa ere idaraya, jinẹ ounjẹ to ni eroja rere ninu, ati sisun nigba to ba yẹ.
Trần Gấm
Anna Huttunen, Finland
Akọṣẹmọṣẹ imọ igbalode nipa ọwọja afẹfẹ oloro carbon.
Gẹgẹ bi ẹni to ni ifẹ si eto irinna ti ko ni ipalara fun ayika, Anna Huttunen jẹ ajijagbara fun gbigbin igi ati eweko si ayika, ati bi igbokegbodo ọkọ yoo ṣe maa lọ lai si ipalara fun awon olugbe ilu Lahti lorilẹede Finland. Ilu Lahti yii ni awon ajọ orilẹede Yuroopu yan gẹgẹ bi olu ilu fun igbelarugẹ igi ati eweko gbingbin lọdun 2021.
Oun gan lo lewaju eto fu didẹkun fifẹ afẹfẹ oloro carbon si ayika nipa agbekalẹ ohun elo app igbalode akọkọ to n fun awọn olugbe ilu naa lanfani ati gba idokoowo to pọ nipa riri I daju pe ilana igbokegbodo ọkọ ti wọn n lo jẹ eyi ti o ṣe anfani fun ayika.
O ṣiṣẹ gẹgẹ bi olubadamoọran fun awon orileede to karamasiki ọrọ ayika ati oju ọjọ labẹ ajọ NetZeroCities. Ajọ yii lo n kun awọn orilẹede ilẹ Yuroopu lọwọ lati rii pe iwa abuku si ayika ati oju ọjọ dopin lọdun 2030.
Hutten n sa ipa ati mu ki ọpọ eeyan karamasiki ilana didẹkun titaare afẹfẹ oloro carbon ai ayika. Bakan naa lo n fọnrere kẹkẹ gigun lati dẹkun afẹfẹ oloro layika. Hutten ri kẹkẹ gẹgẹ bi ọjọ ọla eto irinna lawọn ilu nlanla.
Awọn ilu nlanla kaakiri agbaye kun fun ọpọlọpọ awọn eniyan ti wọn n ṣe ohun meremere lati rii daju pe igbe aye dẹru fun mutumuwa gbotbo. Sa ipa tirẹ, kopa ninu eto isọdọtun yii!
Anna Huttunen
Gladys Kalema-Zikusoka, Uganda
Olutọju ẹranko
Gladys Kalema-Zikusoka, to jẹ gbajugbaja olutọju awọn ẹranko ati oludaabo bo ayika ni Uganda, lo n sa ipa lati daabo bo awọn inanki ori apata to ti fẹẹ tan nilẹ latari bi ayipada oju ọjọ ṣe n ba ibugbe wọn jẹ.
Oun ni oludasilẹ ati oludari ‘Conservation Through Public Health’, ajọ to n ṣe agbatẹru bi awọn eeyan, inanki, atawọn ẹda miran ninu ẹgan ṣe le maa gbe pọ ni alaafia ati ilera pipe.
Lẹyin ọgbọn ọdun, o ti mu ki inanki ori apata to wa ni Uganda o di ẹẹdẹgbẹta lati ọọdunrun, leyi to mu ka ma kawọn kun ẹranko to ti fẹẹ tan lorilẹ mọ.
Ọdun 2021 ni ajọ iṣọkan agbaye to n moju to ọrọ ayika pe Kalema-Zikusoka ‘Aṣiwaju Aye’.
Oun to n fun mi ni ireti lori ọrọ ayipada oju-ọjọ ni ijẹwọ to n gberu si wipe nkan gbudọ di ṣiṣe ni kiakia lori rẹ. Oniruuru ona ni a le gba doju ija kọ rogbodiyan yii ati lati fara mọ.
Gladys Kalema-Zikusoka
Sonia Kastner, US
Ẹrọ to n ṣe awari ibi tina ti n jo
Iṣẹlẹ ina to n jo igbo ṣọṣẹ gan an lọdun yii lawọn igbo nla kaakiri agbaye. Pẹlu bawọn panapana ṣe n tiraka lati dẹkun ina to n jo, Sonia Kaster ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ to n n ṣe iranwọ lati daabo bo wọn.
Pano AI maa n lo sayẹnsi ọgbọn inu lati ṣe ṣe agbekalẹ imọ ijinlẹ ti yoo maa tete jẹ kawọn panapana ri ina pa nipa ṣiṣe aworan ami bi ina ṣe n bẹrẹ ati bawọn eeyan ti n ṣe n tagiri si, dipo ki wọn maa gbẹkẹle awọn eeyan lawujọ lati ṣẹṣẹ maa pe awọn oṣiṣẹ pajawiri.
Kaster ti lo ọdun to le ni ọdun mẹwaa nibi to ti ṣiṣẹ lori oniruuru ẹrọ imọ ijinlẹ.
Ohun to fun mi ni ireti ni agbara ọgbọn inu awọn eeyan ti wọn fi n ṣe oriṣiriiṣi nkan. Mo ti fi oju ara mi ri bawọn eeyan ṣe lo imọ ijinlẹ wa ojutuu si ipa ti ko dara ti iyipada oju ọjọ n ni lori awọn eeyan.
Sonia Kastner
Astrid Linder, Sweden
Ọjọgbọn eto abo oju popo
Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn ileeṣẹ to n ṣe ọkọ ti n lo awọn ere to farajọ ọkunrin lati ṣe ayẹwo bi ọkọ naa yo ṣe daabo bo eeyan si lasiko ijamba, bo tilẹ jẹ iwadii fi han pe obinrin lo n fara gba julọ ninu ijamba ọkọ.
Amojuẹrọ Astrid Linder ti bẹrẹ iṣẹ lati mu ayipada ba eyii, ni bo ṣe bẹrẹ idasilẹ ere to farajọ obinrin fun ayẹwo naa lasiko ijamba. Ere ọhun ni ẹya ara obinrin.
Obinrin naa jẹ Ọjọgbọn nipa eto abo oju popo nileeṣẹ to n ṣe iwadii nipa abo oju popo lorilẹ-ede Sweden, oun naa tun ni igbakeji Ọjọgbọn nipa imọ kan naa nile ẹkọ Chalmers University of Technology.
Neha Mankani, Pakistan
agbẹbi
Nigba ti iṣẹlẹ omiyale kọlu orileẹde Pakistan lọdun to kọja, awọn agbẹbi Neha Mankani rin irinajo lọ si awọn ibi ti ikọlu de ba, lati ṣe iranwọ pẹlu imọ rẹ.
Lati ọwọ ajọ adojutofo rẹ, 'Mama Baby Fund', Mankani ati ẹgbẹ rẹ pese nnkan elo fun ibimọ ati fun awọn igbẹbi fun ẹbi to to ẹgbaa mẹẹdogun.
Nnkan to n ṣe ju ni awọn ibugbe ti iranwọ o de, ti oju ọjọ ṣakoba agbegbe naa.
Mama Baby Fund ti ko owo jọ lati pese ọkọ oju omi ti o maa gbe awọn alaboyun to n gbe lagbegbe si ile iwosan to sunmọ wọn julọ fun iwosan.
Iṣẹ awọn to n gbẹbi ni agbegbe to n koju ijamba to jọ mọ ayipada oju ọjọ ṣe pataki. A jẹ ẹni to n kọkọ de ibi ti ajalu ba ti ṣẹlẹ, a si jẹ ẹni to n ja fun mimojuto ayika pẹlu ti a si ma n ri daju pe awọn obirin n ri itọju to peye gba ṣaaju oyun nini, nipo iloyun ati lẹyin ọmọ bibi, botilẹjẹwipe gbogbo ayika n daru.
Neha Mankani
Wanjira Mathai, Kenya
Olugbanilamọran lori ọrọ ayika
Awokọṣe nla ni Wanjira Mathai jakejado Africa. O le ni ogun ọdun to ti jẹ alagbawi fun ayipada ayika ati awujọ.
Oun ni adari ‘Green Belt Movement’ to jẹ ilumọọka ajọ to n ro awọn obinrin lagbara nipa igi gbigbin ni Kenya. Iya a Wanjiri, Wangari Maathai, to gba ami-ẹyẹ Nobel fun alaafia lọdun 2004, lo da ẹgbẹ naa silẹ.
Lọwọlọwọ yii, Mathai ni adari awọn abaṣepọ ni Africa ati lagbaye fun ‘World Resources Institute’, oun naa si ni alaga ‘Wangari Maathai Foundation’.
Mathai ni olubadamọran lati Africa fun ‘Bezos Earth Fund’, ‘Clean Cooking Alliance’ ati ‘European Climate Foundation’.
Mimu nkan ṣe ni lati bẹrẹ lati ibilẹ. A ni lati ṣatilẹyin fun awọn ipilẹṣẹ ti ibilẹ bi awọn to n d'okoowo igi ati awọn iṣẹ adugbo to n ṣe atunto ayika, awọn oun amuṣagbara ati ọrọ aje. Irufẹ iṣẹ igbiyanju lati ibẹrẹ pẹpẹ bayii ma n fun mi ni ireti nitori wọn ṣafihan oun ti o ṣeeṣe.
Wanjira Mathai
Isabel Farías Meyer, Chile
Olupolongo fawọn obinrin ti wọn tete n dagba lai ṣe nkan oṣu mọ.
Ẹni ọdun mejidinlogun pere ni Isabel Farías Meyer nigba ti nkan oṣu rẹ deede duro ti wọn si sọ pe ile ọmọ rẹ ti kọ iṣẹ silẹ. Iwadii ijinlẹ sọ pe ida kan ninu ọgọrun un obinrin ti koi tii pe ẹni ogoji ọdun ni iru eyi maa n ṣẹlẹ si laye.
Awọn obinrin bayii kii ṣe nkan oṣu mọ ni eyi ti Farias maa n gba wọn niyan ju si. O maa n fi ara rẹ ṣe apẹrẹ ati awọn ohun to ti la kọja laye.
Akọroyin ẹni ọgbọn ọdun yii ti ṣagbekalẹ ajọṣepọ pẹlu awon to n la iru eyi kọja ni Latin America. O maa n pin ifitonileti nipa wọn pẹlu alaye lori awọn ahesọ ti ọpọ n sọ nipa irufẹ iṣẹlẹ yii. O tun n pese iranlọwọ fun awọn to n koju rẹ bayii ni agbegbe rẹ.
Natalie Psaila, Malta
Dokita onimọ iṣegun
Malta ni awọn ofin to le diẹ nipa oyun sisẹ ni ilẹ Europe ati pe Natalie Psaila ma ṣe iranlọwọ fun awọn obinrin to nilo alaye ati imọran.
O wa lara awọn eeyan to ṣe idasile ileese ‘Choice Malta’, to si n ṣe ipolongo lati gbe ogun ti awọn to n gbero lati dena oyun sisẹ, tosi n pe fun ogun lilo to n dena oyun nini
Psaila sọ pe sunmọ igbigbesẹle ni Malta, nibi ti aye ti gba fun anfani ifopinsi ti idunkoko ba ẹmi obinrin, eyi to tumọ si pe awọn obinrin mu awọn oogun laisi amojuto onisegun. O ti ṣeto ẹrọ ibanisọrọ to n ṣe iranlọwọ lati fun awọn obinrin ni atilẹyin ṣaaju, lakoko ati lẹyin iṣẹyun.
O tun kọwe sita sita lori ẹkọ ibalopọ fun awọn ọdọ to wa ni ọmọ ọdun mẹwaa si mọkanla, eyi to pe ‘My Body’s Fantastic Journey, lati ṣe iranlọwọ fun wọn lati loye si nipa ilera ibisi ni orilẹ-ede naa.
Olena Rozvadovska, Ukraine
olupolongo ẹtọ awọn ọmọde
Ṣiṣe iranwọ fawọn ọmọde lati koju iporuru ọkan to tatara ogun wa ni isẹ ti Olena Rozvadovska yan. Oun ni ọkan lara awọn to jijọ da ajọ eleyinju aanu Voices of Children silẹ lati pese itọju fawọn ọmọde
Ọdun 2019 ni wọn bẹrẹ ajọ yi silẹ, lẹyin ti Rozvadovska lọ ṣiṣẹ iranwọ ọfẹ lagbegbe to sunmọ Donbas níbi tí awọn alajangbila ti Russia n satilẹyin fun ti gbogun ti Ukraine.
Ajọ naa ti ni oṣiṣẹ to le ni ọgọrun to n ba ṣiṣẹ lẹka merinla to fi mọ oju opo ipenilọfẹ to si ti n sanfaani fun ogunlọgọ ọmọde ati obi wọn.
Rozvadovska kópa nínú fiimu ti wọn yan lara awọn ti yoo gba ami ẹyẹ Oscars. Akọle rẹ si ni ''A House Made of Splinters.'' Bakan naa awọn alabaṣiṣẹ rẹ tun gbe iwe kan jade ti akọle rẹ n jẹ ''War Through the Voices of Children.''
Rumaitha Al Busaidi, Oman
Onimọ sanyẹnsi
Ọrọ apilẹkọ Rumaitha Al Busaidi nibi eto TED Talk ti ọdun 2021 ti akọle rẹ n jẹ “Women and Girls, You Are Part of the Climate Solution” wa lara nnkan to sọ obinrin naa di gbajumọ nilẹ Arab, iyẹn lẹyin ti awọn eeyan wo ọrọ rẹ ọhun.
Nitori pe o kọṣẹmọṣe, o si ṣe ọpọ akitiyan, o wa lara awọn eeyan to n leke tente ni ẹgbẹ awọn ọdọ ilẹ Arab, iyẹn Arab Youth Council for Climate Change ati ajọ Environment Society of Oman.
O ti fi akoko igba kan gba Aarẹ Amẹrika, Joe Biden nimọran nipa ọrọ oju ọjọ.
Oun ni ọmọ ilẹ Oman to kere julọ to tii tẹ ilẹ South Pole, ati oludasilẹ ajọ WomenX, eyii to n ṣeranwọ fun awọn obinrin ilẹ Arab lati jafafa nidi owo wọn.
Ọna abayọ akọkọ lati bori iṣoro ayipada oju ọjọ ni lati ro awọn obinrin lọmọde-lagba lagbara.
Rumaitha Al Busaidi
Sumini, Indonesia
Alakoso igbo Ọba
Ko wọpọ pe awọn obinrin n dari ni agbegbe ẹya Aceh ni orilẹ-ede Indonesia.
Kete ti Sumini rii pe gige igi nigbo lo n ṣokunfa bi omiyale ṣe n yọ awọn eeyan abule rẹ lẹnu lo ti bẹrẹ si ni sa ipa rẹ lati mojuta ayipada oju ọjọ. Sumini bẹrẹ iṣe pẹlu awọn obinrin bii tirẹ ni abule naa lẹyin to gba aṣẹ lọwọ ileeṣẹ ijọba apapọ to n mojuto awujọ ati igbo Ọba.
Aṣẹ yii lo fun awọn olugbe agbegbe abule Damaran Baru lati maa mojuto ilẹ igbo wọn eyi to tobi yo iwọn eeka 251 fún odun marun un din logoji.
Oun lo si di aṣoju ajọ ti wọn da silẹ nia bule ti wọn pe ni Village Forest Management Unit (LPHK). Eyi to n risi fifopin si gige igi nigbo lọna aitọ, didana sun igi igbo, ki awọn ọlọde maa pa ẹran nigbo lọna aitọ eyi to n mu ẹdinku ba iye ẹkun, ẹyẹ ati awọn ẹranko igbo miran nibẹ.
Erongba rẹ ni pe ki a fopin si gige igi nigbo lọna aitọ, ki a fopin si pipa ẹran igbẹ ninu igbo ati pe ki a fi ọwọsowọpọ lati gbogun ti iṣoro ayipada oju ọjọ, ki a mojuto igbo Óba ati ẹmi awọn ẹranko ninu igbo.
Sumini
Fabiola Trejo, Mexico
Onímọ̀ nípa ìhùwàsí ẹ̀dá ní àwùjọ
Nígbà tí onímọ̀ nípa ìhùwàsí ẹ̀dá ní àwùjọ, Abiola Trejo bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn, kò ì tíì sí iṣẹ́ ìwádìí tó ń tọpinpin bí ìgbádùn ìbálòpọ̀ fún àwọn obìnrin ṣe jẹ́ ohun tó yẹ kí àwùjọ mójútó ní Mexico.
Trejo ló ṣí ojú àwọn ènìyàn si pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀, èyí tó ṣe àgbéyẹ̀wò àìṣedédé àwùjọ, ìfìyàjẹ àwọn obìnrin àti adùn ìbálòpọ̀, tó sì tún pè fún ìgbéga ìṣedédé lórí ìbálòpọ̀ fún àwọn obìnrin.
Ó ní àwọn àìṣedédé kan ló máa ń mú kí àwọn obìnrin kan kìí lè lẹ́nu lórí ìbálòpọ̀. Látara àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìwádìí tó ṣe, ó jẹ́ kí àwọn obìnrin mọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè máa gbà láti fi gbádùn ìbálòpọ̀ àtàwọn ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n bá ń wa ìbálòpọ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ní àwùjọ àwọn Latin America àtàwọn tó ń sọ èdè Spanish tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ìlera obìnrin àti ìbálòpọ̀ dàbí èèwọ̀.
Jennifer Uchendu, Nigeria
Agbẹnusọ lori ilera ọpọlọ
Afojusun ẹgbẹ ọdọ SustyVibes ti Jennifer Uchendu da silẹ ni lati ripe ohun gbogbo fẹsẹmulẹ to sii ṣe fọkan tan.
Jennifer Uchendu lo n ṣiṣẹ lori ipa ti ayipada oju ọjọ ni lori ọpọlọ awọn olugbe ilẹ Africa.
Ni 2022, o da ajọ The Exco-Anxiety Africa Project (TEAP) silẹ lati moju to idaabobo imọlara awọn ọmọ ilẹ adulawọ lẹyin ayipada oju ọjọ nipa iwadi ijinlẹ, ṣiṣe agbawi ati ipolongo nipa ayipada oju ọjọ.
Ohun to jẹẹ logun ni lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn eeyan ati ileeṣẹ to nifẹ si kikọ nipa imọlara ayipada oju ọjọ.
Mo maa n ni iporuru ọkan to ba ti kan ọrọ ayipada oju-ọjọ. Mo ti n gba diẹdiẹ pe ko si bi mo ṣe le gbiyanju to, ko le to, sugbọn mo ṣi le sa agbara mi lati se iwọn ti mo le ṣe. Fifọwọ sowọpọ pẹlu awọn yooku lati gbe igbesẹ ati lati simi pẹlu yoo ṣe ọpọlọpọ iranlọwọ fun mi lati dabobo gbogbo ẹdun ọkan mi nipa bi oju ọjọ ṣe ri.
Jennifer Uchendu
Anamaría Font Villarroel, Venezuela
Onimọni nipa ‘Particle Physics’
Oluwaadi lori ‘particle physics’, ọjọgbọn Anamaría Font Villarroel gbajumọ imọ-jinlẹ ninu ẹkọ‘superstring’, eyi to wa lati ṣalaye gbogbo awọn okuta kekeke.
Iwaadi Font ti jinlẹ ninu oye to dirọ mọ awọn abajade ẹkọ naa lori ọrọ to jẹ mọ atunto ọrọ , eyiti o tun ṣe pataki,to si apejuwe awọn iho dudu ati awọn akoko akọkọ lẹyin ‘Big Bang’.
O ti gba ami ẹyẹ Fundación Polar tẹlẹ ni Venezuela ati pe ọdun yii wọn yan gẹgẹ bi oludije fun ami ẹyẹ awọn obinrin imọ sayẹnsi ni Unesco
Qiyun Woo, Singapore
Asọtan
Gẹgẹ bi alamojuto agbegbe ati oludasilẹ, Qiyun Woo n lo ayelujara lati pin ero nipa ayipada oju ọjọ.
Ikanni rẹ, 'The Wierd and the Wild', dale lori alaye lori imọ nipa oju ọjọ. O dale lori nnkan to maa kọni lẹkọ, to maa mu awọn olugbe sọrọ lori ayipada oju ọjọ.
O jẹ ọkan lara awọn atọkun eto igbohunsafẹfẹ ti o dale lori ẹka 'South East Asia' ti wọn pe ni 'Climate Cheesecake', ti o n lepa lati yanana awọn koko ọrọ ko le ye awọn eeyan.
O tun jẹ 'National Geographic Young Explorer'.
Wahala ayipada oju ọjọ le koko, o bani lẹru. A le koju rẹ pẹlu.
Qiyun Woo
Elham Youssefian, US/Iran
Oludamọran nipa oju ọjọ ati aidape ara
Elham Youssefian, tii se Agbẹjọro to tun jẹ ajafẹtọẹni, ẹni to ni ipenija oju, jẹ ẹni to n fọnrere fun igbesẹ lilọwọ awọ̀n akanda ẹda sinu aayan [lati wa ojutu si ayipada oju ọjọ, paapaa, ta ba n sọrọ nipa gbigbe igbesẹ pajawiri lori isẹlẹ nii se pẹlu oju ọjọ.
Ẹni ti wọn bi, ti wọn si tun tọ dagba ni orilẹede Iran, Youssefian rinrinajo atipo lọ silẹ Amẹrika lọdun 2016. Lonii, obinrin yii n gbe igbesẹ akin ninu ajọ to n wa ajọsepọ awọn eeyan to jẹ akanda ẹda lagbaye, eyi to jẹ ẹgbẹ to ni eto ikansiraẹni laarin awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to le ni ẹẹdẹgbẹfa to n soju awọn eeyan to ni ipenija ara.
Ojuse obinrin naa ni lati se idanilẹkọ fawọn alasẹ lori ojuse wọn gẹgẹ bo se kan ipa ti ayipada oju ọjọ n ni lori awn eeyan to ni ipenija ara. O tun maa n lewaju lati sawari abuda nla tawọn akanda ẹda ni nidi gbigbogun ti isoro to le suyọ lati ipasẹ oju ọjọ.
Awa, gẹgẹ bii ẹda to ni ipenija ara, ti fidi rẹ mulẹ lẹẹkan si nipa abuda wa lati bori awọn isoro to gba ẹlẹgẹ, ka si wa ojutuu si wọn, koda, ko ba a ma fi bẹẹ si isoro kankan nilẹ. Awọn eeyan to ni ipenija ara kaato lati lewaju ninu gbigbe ogun ti ayipada oju ọjọ.
Elham Youssefian
Kini o n je ọgọrun obirin
Lọdọọdun, BBC 100 Women maa n ṣe akojọpọ ọgọrun obirin to laami-laka ti wọn n ṣe oun to moriwu kaakiri agbaye. A ma n ṣe ifọrọwanilenuwo ati ekunrẹrẹ akọsilẹ iroyin nipa aiye wọn - itan ti o fi awọn sipo tente, a o si fi won lede lori gbogbo ikọnni BBC lagbaye.
E kan si ikọnni BBC 100 Women lori Instagram ati Facebook lori aiyelujara ki ẹ si kopa ninu ifọrọwerọ to n lọ nibẹ nipasẹ lilo #BBC100Women
Bawo ni a ṣe yan awon ogorun obirin wonyii?
Ẹgbẹ to n ṣiṣẹ lori BBC 100 Women ṣe akojọpọ awọn orukọ ti wọn yan lẹyin iwadi ati amọran lati ọdọ awọn apapọ ẹgbẹ World Service Languages ati BBC Media Action.
Awọn ti wọn ti kọ iroyin nipa oun ribiribi ti wọn ti gbe ṣe lawujọ tabi awọn ti wọn ti ni ipa lori awọn iroyin pataki lawujọ ni bi osu mejila sẹyin ni a fẹ sawari, pẹlu awọn to ni itan to moriwu lati sọ, tabi ti wọn ti gbe nkan to laami-laka ṣe tabi ti wọn ti ni ipa lori agbegbe wọn lọna ti iroyin le ma ko nipa rẹ.
A se akojọpọ awon orukọ kan, a si gbe wọn yewo lẹgbẹ ọrọ ipilẹ wa fun ti ọdun yii to jẹ - ayipada oju ọjọ ati ipa rẹ to fi sẹgbẹ kan lori obirin ati omodebirin kaakiri agbaye. Lati inu eyi ni a ti yan awọn to bẹ̀rẹ̀ mímojuto ayika ati awọn miran ti wọn n lewaju ninu mimojuto ayika.
A se oju fun awon eeyan kaakiri igun oselu
Akojọpọ awọn to ṣe alakoso lori BBC 100 Women Valeria Perasso, Amelia Butterly, Rebecca Thorn, Paula Adamo Idoeta, Cordelia Hemming, Laura García, Sarah Dias, Lucy Gilder, Mai Kanaaneh, Mark Shea, Vandana Vijay, Kindah Shair, Haya Al Badarneh, Daria Taradai, Lamees Altalebi, Firouzeh Akbarian, Sana Safi, Kateryna Khinkulova, Tamara Gil, Mouna Ba and Chris Clayton.
Oludari BBC 100 Women: Golnoosh Golshani.
Awọn alakoso ti o gbee jade fun World Service Languages: Roberto Belo-Rovella and Carla Rosch.
Awọn ti o to aworan pọ: Prina Shah, Jenny Law, Matt Thomas, Pauline Wilson and Oli Powell.
Development: Prina Shah, Jenny Law, Matt Thomas, Pauline Wilson and Oli Powell.
Awọn eeyan to ni awọn aworan ti a lo ninu akojọpọ yii: Miller Mobley, Maciek Tomiczek/Oxford Atelier, Arati Kumar-Rao, Hamna Haqqi, Craig Kolesky, Pano AI, L. Reid, Benjamin Jones, Yober Arias, Amanda Triplett, Anny Roberts, Diyor Abdughaforzoda, Doi Inthanon Thailand by UTMB, Qinghai Snowland Greatrivers Environmental Protection Association, Jason Boberg, Chaideer Mahyuddin/AFP, New Balance Paraguay, Jo Anne McArthur, The Cartier Women's Initiative (CWI), Lucy Piper, Louise Mabulo, Christian Tasso, Martin Chang, Konstantin Deryagin, Gabriel Quintão, Abel Canizales, Patrick Wally, Sarah Hale, Jimena Mateot, Lucas Christiansen, Hana Walker-Brown, Woody Morris, Xinyan Yu, Chris Parker Edzordzi Sefogaht, Taseer Beyg, Albert Kamanga Zeeya Creations, Salem Solomon, Luke Nugent, R. David Marks, Lee Tinklim, Satu/VTI, FIFA, Josh Finche, Kibuuka Mukisa, Phoebe Xu, Gregory Vepryk, Darko Tomas CROPIX, Wanjira Mathai, Rufat Ergeshov, Osvaldo Fanton, Dani Pujalte, Giuliano Salvatore, Fondation L'Oreal, Daniel Eduardo, Tatyana Egorova, Dovana Films, Jimmy Day/MIT, Editorial Caminho - Leya, Khine Hnin Wai Foundation, Andrew Sikorsky, Ramón Tolosa Calderón, Mariam Siddiqi, Feral Films, Sebastián Aliaga, Diyor Abdughaforzoda, The White Helmets/Syria Civil Defence, Ellie Varley, DGL Nunnery, Mustafa Abumenes, Emanuele Elo Usai, Fazal Raham Arman, Emilia Trejo, Mattia Zoppellaro, Martin Lupton/Light Collective, Yasmina Benslimane, Pavlo Botanov, Marijeta Mojasevic, LenadraPella/International Federation of Sport Climbing, Gal Mosenson, Getty Images.
Ati 450 Itọju Ikẹkọ Ti ara Koko Koko-ọrọ Awọn ọna-aje Awọn ọna Ede Awọn irinṣẹ Nkan Iranlọwọ Wa Indian Indian Internationalization Agbara Agbara. Aṣẹṣẹ dabi pe o ra, laisi itupalẹ. Ushki dabi ẹni pe o n ṣe ipinfunni itọsọna itumọ idanimọ lọwọlọwọ itumọ Amitkumar Sunat ni anfani lati yan itọnisọna eniyan
Nullification ti fẹrẹ pari, ṣugbọn a le pese alaye olumulo. Ṣugbọn ibaraẹnisọrọ ti o pari ti a ko mulẹ ko le fọ, ṣugbọn awọn itọnisọna le ni ilọsiwaju. Akọkọ ni lati ṣetọju agbaye bi awujọ. Ede ni ede ti awujọ.